Neh 10:39
Neh 10:39 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitori awọn ọmọ Israeli ati awọn ọmọ Lefi ni yio mu ọrẹ ọkà wá, ti ọti-waini titun, ati ororo, sinu iyẹwu, nibiti ohun èlo ibi mimọ́ gbe wà, ati awọn alufa ti nṣiṣẹ, ati awọn adèna, ati awọn akọrin: awa kì yio si kọ̀ ile Ọlọrun wa silẹ.
Neh 10:39 Yoruba Bible (YCE)
Àwọn ọmọ Israẹli ati àwọn ọmọ Lefi yóo dá oúnjẹ, waini ati òróró jọ sinu àwọn gbọ̀ngàn, níbi tí àwọn ohun èlò tí a ti yà sí mímọ́ fún lílò ní ilé Ọlọrun wa, pẹlu àwọn alufaa tí wọ́n wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn ati àwọn olùṣọ́ tẹmpili, ati àwọn akọrin. A kò ní fi ọ̀rọ̀ ilé Ọlọrun wa falẹ̀.
Neh 10:39 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àwọn ènìyàn Israẹli, àti àwọn ọmọ Lefi gbọdọ̀ mú ọrẹ oúnjẹ, wáìnì tuntun àti òróró wá sí yàrá ìkó-nǹkan-pamọ́-sí níbi tí a pa ohun èlò ibi mímọ́ mọ́ sí àti ibi tí àwọn àlùfáà tí ń ṣe ìránṣẹ́ lọ́wọ́, àwọn aṣọ́nà àti àwọn akọrin máa ń dúró sí. “Àwa kì yóò gbàgbé tàbí ṣe àìbìkítà nípa ilé Ọlọ́run wa.”