Neh 13:1-2
Neh 13:1-2 Bibeli Mimọ (YBCV)
LI ọjọ na, a kà ninu iwe Mose li eti gbogbo enia, ati ninu rẹ̀ li a ri pe, ki ara Ammoni ati ara Moabu ki o má wá sinu ijọ Ọlọrun lailai; Nitoriti nwọn kò fi onjẹ ati omi ko awọn ọmọ Israeli lọna, ṣugbọn nwọn bẹ̀ Balaamu lọwẹ si wọn, lati fi wọn gegun: ṣugbọn Ọlọrun wa sọ egun na di ibukun.
Neh 13:1-2 Yoruba Bible (YCE)
Ní ọjọ́ náà, wọ́n kà ninu ìwé Mose sí etígbọ̀ọ́ àwọn eniyan, ibẹ̀ sì ni a ti rí i kà pé àwọn ará Amoni ati àwọn ọmọ Moabu kò gbọdọ̀ wọ àwùjọ àwọn eniyan Ọlọrun, nítorí pé wọn kò gbé oúnjẹ ati omi lọ pàdé àwọn ọmọ Israẹli, kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n bẹ Balaamu lọ́wẹ̀ láti máa gbé àwọn ọmọ Israẹli ṣépè, ṣugbọn Ọlọrun wa yí èpè náà pada sí ìre fún Israẹli.
Neh 13:1-2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní ọjọ́ náà ni a ka ìwé Mose sókè sí etí ìgbọ́ àwọn ènìyàn, nínú rẹ̀ ni a ti rí i tí a kọ ọ́ sílẹ̀ pé a kò gbọdọ̀ gba àwọn ará a Ammoni tàbí àwọn ará a Moabu sí àárín ìjọ ènìyàn Ọlọ́run láéláé. Nítorí wọn kò mú oúnjẹ àti omi wá pàdé àwọn ọmọ Israẹli lọ́nà, dípò bẹ́ẹ̀, wọ́n bẹ Balaamu ní ọ̀wẹ̀ láti gégùn ún lé wọn lórí (Ṣùgbọ́n Ọlọ́run wa yí ègún náà padà sí ìbùkún).