Neh 7:1-2
Neh 7:1-2 Yoruba Bible (YCE)
Lẹ́yìn tí a ti mọ odi náà tán, tí mo ti ṣe àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀, tí mo sì ti yan àwọn olùṣọ́ ẹnu ọ̀nà, ati àwọn akọrin ati àwọn ọmọ Lefi, mo yan arakunrin mi, Hanani, ati Hananaya, gomina ilé ìṣọ́, láti máa ṣe àkóso Jerusalẹmu, nítorí pé Hananaya jẹ́ olóòótọ́ ó sì bẹ̀rù Ọlọrun ju ọpọlọpọ àwọn yòókù lọ.
Neh 7:1-2 Bibeli Mimọ (YBCV)
O SI ṣe, nigbati a mọ odi na tan, ti mo si gbe ilẹkùn ro, ti a si yan awọn oludena ati awọn akọrin, ati awọn ọmọ Lefi, Mo si fun Hanani arakunrin mi, ati Hananiah ijòye ãfin, li aṣẹ lori Jerusalemu: nitori olododo enia li o ṣe, o si bẹ̀ru Ọlọrun jù enia pupọ lọ.
Neh 7:1-2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Lẹ́yìn ìgbà tí a tún odi mọ tán tí mo sì ri àwọn ìlẹ̀kùn sí ààyè wọn, a sì yan àwọn aṣọ́bodè, àwọn akọrin àti àwọn Lefi. Mo fún Hanani arákùnrin mi pẹ̀lú Hananiah olórí ilé ìṣọ́ ní àṣẹ lórí Jerusalẹmu, nítorí tí ó jẹ́ ènìyàn olóòtítọ́, ó sì bẹ̀rù Ọlọ́run jù bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ti ṣe lọ.