Neh 9:16-17
Neh 9:16-17 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn awọn ati awọn baba wa hu ìwa igberaga, nwọn si mu ọrùn wọn le, nwọn kò si gba ofin rẹ gbọ́. Nwọn si kọ̀ lati gbọràn, bẹ̃ni nwọn kò ranti iṣẹ iyanu ti iwọ ṣe li ãrin wọn; ṣugbọn nwọn mu ọrùn wọn le, ninu ìṣọtẹ wọn, nwọn yan olori lati pada si oko-ẹrú wọn: ṣugbọn iwọ li Ọlọrun ti o mura lati dariji, olore ọfẹ, ati alãnu, o lọra lati binu, o si ṣeun pipọ̀, o kò si kọ̀ wọn silẹ.
Neh 9:16-17 Yoruba Bible (YCE)
“Àwọn ati àwọn baba wa hùwà ìgbéraga, wọn ṣe orí kunkun, wọn kò sì pa òfin náà mọ́. Wọ́n kọ̀ wọn kò gbọ́ràn, wọn kò sì ranti àwọn ohun ìyanu tí o ṣe láàrin wọn, ṣugbọn wọ́n ṣoríkunkun, wọ́n sì yan olórí láti kó wọn pada sinu ìgbèkùn wọn ní Ijipti. Ṣugbọn Ọlọrun tíí dáríjì ni ni Ọ́, olóore ọ̀fẹ́ ati aláàánú sì ni ọ́, o kì í tètè bínú, o sì kún fún ìfẹ́ tí kìí yẹ̀, nítorí náà o kò kọ̀ wọ́n sílẹ̀.
Neh 9:16-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Ṣùgbọ́n àwọn, baba ńlá wa, wọ́n ṣe ìgbéraga, wọ́n sì ṣe agídí, wọn kò sì tẹríba fún àwọn ìlànà rẹ. Wọ́n kọ̀ láti fetísílẹ̀, wọ́n sì kùnà láti rántí iṣẹ́ ìyanu tí ìwọ ṣe ní àárín wọn. Wọ́n ṣe agídí, nínú ìṣọ̀tẹ̀ wọn, wọ́n yan olórí láti padà sí oko ẹrú wọn. Ṣùgbọ́n ìwọ Ọlọ́run tí ó ń dáríjì, olóore-ọ̀fẹ́ àti aláàánú, ó lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ ní ìfẹ́. Nítorí náà ìwọ kò sì kọ̀ wọ́n sílẹ̀