Ṣe àfiwé gbogbo èyà
Num 4:7YBCV(Bibeli Mimọ)
Ati lori tabili àkara ifihàn nì, ki nwọn ki o nà aṣọ alaró kan si, ki nwọn ki o si fi awopọkọ sori rẹ̀, ati ṣibi ati awokòto, ati ìgo ohun didà: ati àkara ìgbagbogbo nì ki o wà lori rẹ̀
Pín
Num 4YBCVNum 4:7BMYO(Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Lórí tábìlì àkàrà ìfihàn ni kí wọn ó na aṣọ aláró kan sí, kí wọn kí ó sì fi àwopọ̀kọ́ sórí rẹ̀, àti ṣíbí àti àwokòtò àti ìgò fún ọrẹ ohun mímu; àti àkàrà ìgbà gbogbo ní kí ó wà lórí rẹ̀.
Pín
Num 4BMYONum 4:7YCE(Yoruba Bible)
“Wọn yóo da aṣọ aláwọ̀ aró bo tabili tí burẹdi ìfihàn máa ń wà lórí rẹ̀. Lẹ́yìn náà, wọn yóo kó àwọn nǹkan wọnyi lé e lórí: àwọn àwo turari, àwọn àwokòtò, ati àwọn ìgò fún ọtí ìrúbọ. Burẹdi ìfihàn sì gbọdọ̀ wà lórí rẹ̀ nígbà gbogbo.
Pín
Num 4YCE