Owe 13:1-12

Owe 13:1-12 Yoruba Bible (YCE)

Ọlọ́gbọ́n ọmọ a máa gba ẹ̀kọ́ baba rẹ̀, ṣugbọn ẹlẹ́yà kì í gbọ́ ìbáwí. Eniyan rere a máa rí ire nítorí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀, ṣugbọn ohun tí àwọn ẹlẹ́tàn ń fẹ́ ni ìwà jàgídíjàgan. Ẹni tí ó ń ṣọ́ ẹnu rẹ̀, ẹ̀mí ara rẹ̀ ni ó ń ṣọ́, ẹni tí ń sọ̀rọ̀ àsọjù yóo parun. Ọkàn ọ̀lẹ ń fẹ́ nǹkan, ṣugbọn kò ní rí i, ṣugbọn ẹni tí ń fi tọkàntọkàn ṣiṣẹ́ yóo ní ọpọlọpọ nǹkan. Olóòótọ́ a máa kórìíra èké, ṣugbọn eniyan burúkú a máa hùwà ìtìjú ati àbùkù. Òdodo a máa dáàbò bo ẹni tí ọ̀nà rẹ̀ bá tọ́, ṣugbọn ẹ̀ṣẹ̀ a máa bi eniyan burúkú ṣubú. Ẹnìkan ń ṣe bí ọlọ́rọ̀, bẹ́ẹ̀ kò ní nǹkankan, níbẹ̀ ni ẹlòmíràn ń ṣe bíi talaka, ṣugbọn tí ó ní ọpọlọpọ ọrọ̀. Ọlọ́rọ̀ a máa fi ohun ìní rẹ̀ ra ẹ̀mí rẹ̀ pada, ṣugbọn talaka kì í tilẹ̀ gbọ́ ìbáwí. Ìmọ́lẹ̀ olódodo a máa fi ayọ̀ tàn, ṣugbọn fìtílà eniyan burúkú yóo kú. Ìjà ni ìgbéraga máa ń fà, ṣugbọn àwọn tí wọ́n bá gba ìmọ̀ràn yóo ní ọgbọ́n. Ọrọ̀ tí a fi ìkánjú kójọ kì í pẹ́ dínkù, ṣugbọn ẹni tí ó bá fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ kó ọrọ̀ jọ yóo máa ní àníkún. Bí ìrètí bá pẹ́ jù, a máa kó àárẹ̀ bá ọkàn, ṣugbọn kí á tètè rí ohun tí à ń fẹ́ a máa mú ara yá gágá.

Owe 13:1-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ọlọ́gbọ́n ọmọ gba ẹ̀kọ́ baba rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹlẹ́gàn kò gbọ́ ìbáwí. Láti inú èso ẹnu rẹ̀ ènìyàn ń gbádùn ohun rere ṣùgbọ́n, ìfẹ́ ọkàn aláìṣòótọ́ ní ìwà ipá. Ẹnikẹ́ni tí ó ṣọ́ ẹnu rẹ̀ pa ẹnu ara rẹ̀ mọ́, ṣùgbọ́n ẹni tí ó ń sọ̀rọ̀ gbàù gbàù yóò parun. Ọkàn ọ̀lẹ ń fẹ́, ṣùgbọ́n kò rí nǹkan kan, ṣùgbọ́n ọkàn àwọn ti kì í ṣe ọ̀lẹ rí ìtẹ́lọ́rùn. Olódodo kórìíra ohun tí í ṣe irọ́ Ṣùgbọ́n ènìyàn búburú hu ìwà ìríra àti ìtìjú. Òdodo ń ṣamọ̀nà ènìyàn olóòtítọ́ inú, ṣùgbọ́n ìwà búburú ṣí ẹlẹ́ṣẹ̀ ní ipò. Ènìyàn kan díbọ́n bí ẹni tí ó ní ọrọ̀ síbẹ̀ kò ní nǹkan kan ẹlòmíràn díbọ́n bí i tálákà, síbẹ̀ ó ní ọrọ̀ púpọ̀. Ọrọ̀ ènìyàn le è ra ẹ̀mí rẹ̀ ṣùgbọ́n tálákà kì í gbọ́ ìdẹ́rùbà. Ìmọ́lẹ̀ olódodo tàn roro, ṣùgbọ́n fìtílà ènìyàn búburú ni a pa kú. Ìgbéraga máa ń dá ìjà sílẹ̀ ni ṣùgbọ́n ọgbọ́n wà nínú àwọn tí ń gba ìmọ̀ràn. Owó tí a fi ọ̀nà èrú kójọ yóò ṣí lọ, ṣùgbọ́n ẹni tí ń kó owó jọ díẹ̀díẹ̀ yóò pọ̀ sí i. Ìrètí tí ń falẹ̀ máa ń mú kí ọkàn ṣàárẹ̀ ṣùgbọ́n ìrètí tí a rí gbà jẹ́ igi ìyè.