Owe 6:16-19
Owe 6:16-19 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ohun mẹfa li Oluwa korira: nitõtọ, meje li o ṣe irira fun ọkàn rẹ̀: Oju igberaga, ète eke, ati ọwọ ti nta ẹ̀jẹ alaiṣẹ silẹ, Aiya ti nhumọ buburu, ẹsẹ ti o yara ni ire sisa si ìwa-ika, Ẹlẹri eke ti nsọ eke jade, ati ẹniti ndá ìja silẹ larin awọn arakunrin.
Owe 6:16-19 Yoruba Bible (YCE)
Àwọn nǹkan mẹfa kan wà tí OLUWA kò fẹ́: wọ́n tilẹ̀ tó meje tí ó jẹ́ ohun ìríra fún un: Ìgbéraga, irọ́ pípa, ẹni tí ń déédé pa aláìṣẹ̀, ọkàn tí ń pète ìkà, ẹsẹ̀ tí ń sáré sí ibi, ẹlẹ́rìí èké tí ẹnu rẹ̀ kún fún irọ́, ati ẹni tí ń dá ìjà sílẹ̀ láàrin eniyan.
Owe 6:16-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àwọn ohun mẹ́fà wà tí OLúWA kórìíra, ohun méje ní ó jẹ́ ìríra sí i: Ojú ìgbéraga, Ahọ́n tó ń parọ́ ọwọ́ tí ń ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀, ọkàn tí ń pète ohun búburú, ẹsẹ̀ tí ó yára láti sáré sínú ìwà ìkà, Ajẹ́rìí èké tí ń tú irọ́ jáde lẹ́nu àti ènìyàn tí ń dá ìjà sílẹ̀ láàrín àwọn ọmọ ìyá kan.