O. Daf 23:1-6
O. Daf 23:1-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
OLUWA li Oluṣọ-agutan mi; emi kì yio ṣe alaini. O mu mi dubulẹ ninu papa-oko tutù; o mu mi lọ si iha omi didakẹ rọ́rọ́. O tù ọkàn mi lara; o mu mi lọ nipa ọ̀na ododo nitori orukọ rẹ̀. Nitõtọ, bi mo tilẹ nrìn larin afonifoji ojiji ikú, emi kì yio bẹ̀ru ibi kan; nitori ti Iwọ pẹlu mi; ọgọ rẹ ati ọpá rẹ nwọn ntù mi ninu. Iwọ tẹ́ tabili onjẹ silẹ niwaju mi li oju awọn ọta mi; iwọ dà ororo si mi li ori; ago mi si kún akúnwọsilẹ. Nitotọ, ire ati ãnu ni yio ma tọ̀ mi lẹhin li ọjọ aiye mi gbogbo; emi o si ma gbe inu ile Oluwa lailai.
O. Daf 23:1-6 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA ni Olùṣọ́-aguntan mi, n kò ní ṣe àìní ohunkohun. Ó mú mi dùbúlẹ̀ ninu pápá koríko tútù, ó mú mi lọ sí ibi tí omi ti dákẹ́ rọ́rọ́; ó sọ agbára mi dọ̀tun. Ó tọ́ mi sí ọ̀nà òdodo nítorí orúkọ rẹ̀. Àní, bí mo tilẹ̀ ń rìn ninu òkùnkùn létí bèbè ikú, n kò ní bẹ̀rù ibi kankan; nítorí tí o wà pẹlu mi; ọ̀gọ rẹ ati ọ̀pá rẹ ń fi mí lọ́kàn balẹ̀. O gbé oúnjẹ kalẹ̀ níwájú mi, níṣojú àwọn ọ̀tá mi; o da òróró sí mi lórí; o sì bu ife mi kún ní àkúnwọ́sílẹ̀. Dájúdájú, ire ati àánú yóo máa tẹ̀lé mi kiri, ní gbogbo ọjọ́ ayé mi; èmi óo sì máa gbé inú ilé OLUWA laelae.
O. Daf 23:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
OLúWA ni Olùṣọ́ èmi àgùntàn rẹ̀, èmi kì yóò ṣe aláìní. Ó mú mi dùbúlẹ̀ sí ibi pápá oko tútù Ó mú mi lọ sí ibi omi dídákẹ́ rọ́rọ́; Ó mú ọkàn mi padà bọ̀ sípò Ó mú mi lọ sí ọ̀nà òdodo nítorí orúkọ rẹ̀. Bí mo tilẹ̀ ń rìn Láàrín àfonífojì òjìji ikú, èmi kì yóò bẹ̀rù ibi kan; nítorí ìwọ wà pẹ̀lú mi; ọ̀gọ rẹ àti ọ̀pá à rẹ wọ́n ń tù mí nínú. Ìwọ tẹ́ tábìlì oúnjẹ sílẹ̀ níwájú mi ní ojú àwọn ọ̀tá à mi; ìwọ ta òróró sí mi ní orí; ago mí sì kún àkúnwọ́sílẹ̀. Nítòótọ́, ìre àti àánú ni yóò máa tọ̀ mí lẹ́yìn ní ọjọ́ ayé è mi gbogbo, èmi yóò sì máa gbé inú ilé OLúWA títí láéláé.