O. Daf 45:1-17
O. Daf 45:1-17 Bibeli Mimọ (YBCV)
AIYA mi nhumọ̀ ọ̀ran rere: emi nsọ ohun ti mo ti ṣe, fun ọba ni: kalamu ayawọ akọwe li ahọn mi. Iwọ yanju jù awọn ọmọ enia lọ: a dà ore-ọfẹ si ọ li ète: nitorina li Ọlọrun nbukún fun ọ lailai. San idà rẹ mọ idi rẹ, Alagbara julọ, ani ogo rẹ ati ọlá-nla rẹ. Ati ninu ọlánlá rẹ ma gẹṣin lọ li alafia, nitori otitọ ati ìwa-tutu ati ododo; ọwọ ọtún rẹ yio si kọ́ ọ li ohun ẹ̀ru. Ọfa rẹ mu li aiya awọn ọta ọba; awọn enia nṣubu nisalẹ ẹsẹ rẹ. Ọlọrun, lai ati lailai ni itẹ́ rẹ: ọpá-alade ijọba rẹ, ọpá-alade otitọ ni. Iwọ fẹ ododo, iwọ korira ìwa-buburu: nitori na li Ọlọrun, Ọlọrun rẹ, ṣe fi àmi ororo ayọ̀ yà ọ ṣolori awọn ọ̀gba rẹ. Gbogbo aṣọ rẹ li o nrun turari, ati aloe, ati kassia, lati inu ãfin ehin-erin jade ni nwọn gbe nmu ọ yọ̀. Awọn ọmọbinrin awọn alade wà ninu awọn ayanfẹ rẹ: li ọwọ ọtún rẹ li ayaba na gbe duro ninu wura Ofiri. Dẹti silẹ, ọmọbinrin, si ronu, si dẹ eti rẹ silẹ! gbagbe awọn enia rẹ, ati ile baba rẹ! Bẹ̃li Ọba yio fẹ ẹwà rẹ gidigidi: nitori on li Oluwa rẹ; ki iwọ ki o si ma sìn i. Ọmọbinrin Tire ti on ti ọrẹ; ati awọn ọlọrọ̀ ninu awọn enia yio ma bẹ̀bẹ oju-rere rẹ. Ti ogo ti ogo li ọmọbinrin ọba na ninu ile: iṣẹ wura ọnà abẹrẹ li aṣọ rẹ̀. Ninu aṣọ iṣẹ ọnà abẹrẹ li a o mu u tọ̀ ọba wá: awọn wundia, ẹgbẹ rẹ̀ ti ntọ̀ ọ lẹhin li a o mu tọ̀ ọ wá. Pẹlu inu didùn ati pẹlu ayọ̀ li a o fi mu wọn wá: nwọn o si wọ̀ ãfin ọba lọ. Nipò awọn baba rẹ li awọn ọmọ rẹ yio wà, ẹniti iwọ o ma fi jẹ oye lori ilẹ gbogbo. Emi o ma ṣe orukọ rẹ ni iranti ni iran gbogbo: nitorina li awọn enia yio ṣe ma yìn ọ lai ati lailai.
O. Daf 45:1-17 Yoruba Bible (YCE)
Èrò rere kan ń gbé mi lọ́kàn, mò ń kọ orin mi fún ọba ahọ́n mi dàbí gègé akọ̀wé tó mọṣẹ́. Ìwọ ni o dára jùlọ láàrin àwọn ọkunrin; ọ̀rọ̀ dùn lẹ́nu rẹ, nítorí náà Ọlọrun ti bukun ọ títí ayé. Sán idà rẹ mọ́ ìdí, ìwọ alágbára, ninu ògo ati ọlá ńlá rẹ. Máa gun ẹṣin ìṣẹ́gun lọ ninu ọlá ńlá rẹ, máa jà fún òtítọ́ ati ẹ̀tọ́, kí ọwọ́ ọ̀tún rẹ fún ọ ní ìṣẹ́gun ńlá. Àwọn ọfà rẹ mú, wọ́n gún àwọn ọ̀tá ọba lọ́kàn, àwọn eniyan ń wó lulẹ̀ níwájú rẹ. Ìjọba tí Ọlọrun fún ọ wà lae ati laelae. Ọ̀pá àṣẹ rẹ, ọ̀pá àṣẹ ẹ̀tọ́ ni. O fẹ́ràn òdodo, o sì kórìíra ìwà ìkà nítorí náà ni Ọlọrun, àní Ọlọrun rẹ, ṣe fi àmì òróró yàn ọ́. Àmì òróró ayọ̀ ni ó fi gbé ọ ga ju àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ lọ. Aṣọ rẹ kún fún òórùn oríṣìíríṣìí turari, láti inú ààfin tí a fi eyín erin ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ ni wọ́n tí ń fi ohun èlò ìkọrin olókùn dá ọ lára yá. Àwọn ọmọ ọba wà lára àwọn obinrin inú àgbàlá rẹ, ayaba dúró ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ, ó fi ojúlówó wúrà ṣe ọ̀ṣọ́ sára. Gbọ́, ìwọ ọmọbinrin, ronú kí o sì tẹ́tí sílẹ̀, gbàgbé àwọn eniyan rẹ ati ilé baba rẹ; ẹwà rẹ yóo sì mú ọ wu ọba; òun ni oluwa rẹ, nítorí náà bu ọlá fún un. Àwọn ará Tire yóo máa fi ẹ̀bùn wá ojurere rẹ, àní, àwọn eniyan tí wọ́n ní ọrọ̀ jùlọ. Yóo máa wá ojurere rẹ, pẹlu oríṣìíríṣìí ọrọ̀. Ọmọ ọbabinrin fi aṣọ wúrà ṣọ̀ṣọ́ jìngbìnnì ninu yàrá rẹ̀, ó wọ aṣọ aláràbarà, a mú un lọ sọ́dọ̀ ọba, pẹlu àwọn wundia ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ tí wọn ń sìn ín lọ. Pẹlu ayọ̀ ati inú dídùn ni a fi ń mú wọn lọ, bí wọ́n ṣe ń wọ ààfin ọba. Àwọn ọmọkunrin rẹ ni yóo rọ́pò àwọn baba rẹ; o óo fi wọ́n jọba káàkiri gbogbo ayé. N óo mú kí á máa ki oríkì rẹ láti ìran dé ìran; nítorí náà àwọn eniyan yóo máa yìn ọ́ lae ati laelae.
O. Daf 45:1-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọkàn mi mọ ọ̀rọ̀ rere gẹ́gẹ́ bí mo ṣe ń sọ ohun tí mo ti ṣe fún ọba ahọ́n mi ni kálámù ayára kọ̀wé. Ìwọ yanjú ju àwọn ọmọ ènìyàn lọ: a da oore-ọ̀fẹ́ sí ọ ní ètè: nítorí náà ni Ọlọ́run ṣe bùkún fún ọ láéláé. Gba idà rẹ mọ́ ìhà rẹ, ìwọ alágbára jùlọ wọ ara rẹ ní ògo àti ọláńlá. Nínú ọláńlá rẹ, máa gẹṣin lọ ní àlàáfíà lórí òtítọ́, ìwà tútù àti òtítọ́ jẹ́ kí ọwọ́ ọ̀tún rẹ ṣe ohun ẹ̀rù. Jẹ́ kí ọfà mímú rẹ̀ dá ọkàn àwọn ọ̀tá ọba lu jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè ṣubú sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀. Ọlọ́run láé, àti láéláé ni ìtẹ́ rẹ, ọ̀pá aládé ìjọba rẹ, ọ̀pá aládé òtítọ́ ni. Ìwọ fẹ́ olódodo, ìwọ sì kórìíra ìwà búburú nígbà náà Ọlọ́run, Ọlọ́run rẹ ti yàn ọ́ ṣe olórí àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ, nípa fífi ààmì òróró ayọ̀ kùn ọ́. Gbogbo aṣọ rẹ̀ ni ó ń rùn pẹ̀lú òjìá àti aloe àti kasia; láti inú ààfin tí a fi eyín erin ṣe orin olókùn tẹ́ẹ́rẹ́ mú inú rẹ̀ dùn. Àwọn ọmọbìnrin àwọn ọba wà nínú àwọn àyànfẹ́ rẹ̀, ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ ni ayaba náà gbé dúró nínú wúrà ofiri. Gbọ́ ìwọ ọmọbìnrin, ronú kí o sì dẹtí rẹ sí mi gbàgbé àwọn ènìyàn rẹ àti ilé baba rẹ Bẹ́ẹ̀ ni ọba yóò fẹ́ ẹwà rẹ gidigidi nítorí òun ni olúwa rẹ kí ìwọ sì máa tẹríba fún un. Ọmọbìnrin ọba Tire yóò wá pẹ̀lú ẹ̀bùn àwọn ọkùnrin ọlọ́rọ̀ yóò máa wá ojúrere rẹ̀. Gbogbo ògo ni ti ọmọbìnrin ọba ní àárín ilé rẹ̀, iṣẹ́ wúrà ọnà abẹ́rẹ́ ní aṣọ rẹ̀. Nínú aṣọ olówó iyebíye ni a mú un tọ́ ọba wá, àwọn wúńdíá ẹgbẹ́ rẹ̀ tẹ̀lé e, wọ́n sí mú un tọ̀ ọ́ wá. Wọ́n sì mú un wá pẹ̀lú ayọ̀ àti inú dídùn wọ́n sì wọ ààfin ọba. Ọmọ rẹ̀ ni yóò gba ipò baba rẹ̀ ìwọ yóò sì fi wọ́n joyè lórí ilẹ̀ gbogbo. Èmí yóò máa rántí orúkọ rẹ̀ ní ìran gbogbo, nígbà náà ni orílẹ̀-èdè yóò yìn ọ́ láé àti láéláé.