Ṣe àfiwé gbogbo èyà
O. Daf 59:9-10YBCV(Bibeli Mimọ)
Agbara rẹ̀ li emi o duro tì: nitori Ọlọrun li àbo mi. Ọlọrun ãnu mi ni yio ṣaju mi: Ọlọrun yio jẹ ki emi ri ifẹ mi lara awọn ọta mi.
O. Daf 59:9-10BMYO(Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìwọ agbára mi, èmi ó máa kọrin ìyìn sí ọ; nítorí ìwọ Ọlọ́run ni ààbò mi, Ọlọ́run àánú mi ni yóò ṣáájú mi. Ọlọ́run yóò sì jẹ́ kí èmi rí ìfẹ́ mi lára àwọn ọ̀tá mi. Yóò sì jẹ́ kí n yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun lórí ìfẹ́ àwọn ọ̀tá mi.
O. Daf 59:9-10YCE(Yoruba Bible)
Ọlọrun, agbára mi, ojú rẹ ni mò ń wò, nítorí ìwọ, Ọlọrun, ni odi mi. Ọlọrun mi óo wá sọ́dọ̀ mi ninu ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀; Ọlọrun óo fún mi ní ìṣẹ́gun lórí àwọn ọ̀tá mi.
Pín
O. Daf 59YCE