Àmì Ìdánimọ̀ Ohun-èlò Bíbélì
Ṣe Àwárí

Ṣe àfiwé gbogbo èyà

O. Daf 61:1-2YBCV(Bibeli Mimọ)

GBỌ́ ẹkún mi, Ọlọrun; fiye si adura mi. Lati opin aiye wá li emi o kigbe pè ọ, nigbati o rẹ̀ aiya mi, fà mi lọ si apata ti o ga jù mi lọ.

O. Daf 61:1-2BMYO(Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)

Gbọ́ ẹkún mi, Ọlọ́run; tẹ́tí sí àdúrà mi. Láti òpin ayé wá ni èmi yóò pè ọ́, mo pè nígbà àyà mi ń ṣàárẹ̀; mú mi lọ sí ibi àpáta tí ó ga jù mí lọ.

O. Daf 61:1-2YCE(Yoruba Bible)

Gbọ́ igbe mi, Ọlọrun, fetí sí adura mi. Láti ọ̀nà jíjìn réré ni mo ti ké pè ọ́, nígbà tí àárẹ̀ mú mi. Tọ́ mi lọ sí ibi àpáta tí ó ga jù mí lọ