Ifi 12:14-16
Ifi 12:14-16 Bibeli Mimọ (YBCV)
A si fi apá iyẹ́ meji ti idì nla na fun obinrin na, pe ki o fò lọ si aginjù, si ipò rẹ̀, nibiti a gbé bọ́ ọ fun akoko kan ati fun awọn akoko, ati fun idaji akoko kuro lọdọ ejò na. Ejò na si tú omi jade lati ẹnu rẹ̀ wá bi odo nla sẹhin obinrin na, ki o le mu ki ìṣan omi na gbá a lọ. Ilẹ si ràn obinrin na lọwọ, ilẹ si yà ẹnu rẹ̀, o si fi ìṣan omi na mu, ti dragoni na tú jade lati ẹnu rẹ̀ wá.
Ifi 12:14-16 Yoruba Bible (YCE)
Ni a bá fún obinrin náà ní ìyẹ́ idì ńláńlá meji, kí ó lè fò lọ sí aṣálẹ̀ níbi tí wọ́n ti ń tọ́jú rẹ̀ fún ọdún mẹta ati oṣù mẹfa, tí ó fi bọ́ lọ́wọ́ ejò náà. Ni ejò yìí bá tú omi jáde lẹ́nu bí odò, kí omi lè gbé obinrin náà lọ. Ṣugbọn ilẹ̀ ran obinrin náà lọ́wọ́. Ilẹ̀ lanu, ó fa omi tí Ẹranko Ewèlè náà tu jáde lẹ́nu mu.
Ifi 12:14-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
A sì fi apá ìyẹ́ méjì tí idì ńlá náà fún obìnrin náà, pé kí ó fò lọ sí aginjù, sí ipò rẹ̀, níbi tí a ó gbe bọ ọ fún àkókò kan àti fún àwọn àkókò, àti fún ìdajì àkókò kúrò lọ́dọ̀ ejò náà. Ejò náà sì tu omi jáde láti ẹnu rẹ̀ wá bí odò ńlá sẹ́yìn obìnrin náà, kí ó lè fi ìṣàn omi náà gbà á lọ. Ilẹ̀ sì ran obìnrin náà lọ́wọ́, ilẹ̀ sì ya ẹnu rẹ̀, ó sì fi ìṣàn omi náà mú, tí dragoni náà tu jáde láti ẹnu rẹ̀ wá.