Ifi 14:9-11
Ifi 14:9-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
Angẹli kẹta si tẹle wọn, o nwi li ohùn rara pe, Bi ẹnikẹni ba nforibalẹ fun ẹranko nì, ati aworan rẹ̀, ti o si gbà àmi si iwaju rẹ̀ tabi si ọwọ́-rẹ̀, On pẹlu yio mu ninu ọti-waini ibinu Ọlọrun, ti a tú jade li aini àbula sinu ago irunu rẹ̀; a o si fi iná ati sulfuru da a loró niwaju awọn angẹli mimọ́, ati niwaju Ọdọ-Agutan: Ẹ̃fin oró wọn si nlọ soke titi lailai, nwọn kò si ni isimi li ọsán ati li oru, awọn ti nforibalẹ fun ẹranko na ati fun aworan rẹ̀, ati ẹnikẹni ti o ba si gbà àmi orukọ rẹ̀.
Ifi 14:9-11 Yoruba Bible (YCE)
Angẹli kẹta wá tẹ̀lé wọn. Ó kígbe pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá júbà ẹranko náà ati ère rẹ̀, tí ó gba àmì rẹ̀ siwaju rẹ̀ tabi sí ọwọ́ rẹ̀, yóo mu ninu ògidì ọtí ibinu Ọlọrun, tí ó wà ninu ife ibinu rẹ̀. Olúwarẹ̀ yóo joró ninu iná àjóòkú níwájú àwọn angẹli mímọ́ ati Ọ̀dọ́ Aguntan. Èéfín iná oró àwọn tí wọ́n bá júbà ẹranko náà ati ère rẹ̀, tí wọ́n gba àmì orúkọ rẹ̀, yóo máa rú títí lae. Kò ní rọlẹ̀ tọ̀sán-tòru.”
Ifi 14:9-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Angẹli mìíràn, ẹ̀kẹta, sì tẹ̀lé wọn, ó ń wí ni ohùn rara pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá ń foríbalẹ̀ fún ẹranko náà àti àwòrán rẹ̀, tí ó sì gba ààmì sí iwájú orí rẹ̀ tàbí sí ọwọ́ rẹ̀. Òun pẹ̀lú yóò mú nínú ọtí wáìnì ìbínú Ọlọ́run, tí a dà ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ sínú ago ìrunú rẹ̀; a ó sì fi iná sulfuru dá a lóró níwájú àwọn angẹli mímọ́, àti níwájú Ọ̀dọ́-àgùntàn: Èéfín ìdálóró wọn ń lọ sókè títí láéláé wọn kò sì ní ìsinmi ni ọ̀sán àti ní òru, àwọn tí ń foríbalẹ̀ fún ẹranko náà àti fún àwòrán rẹ̀, àti ẹnikẹ́ni tí o ba sì gba ààmì orúkọ rẹ̀.”