Ifi 19:20
Ifi 19:20 Bibeli Mimọ (YBCV)
A si mu ẹranko na, ati woli eke nì pẹlu rẹ̀, ti o ti nṣe iṣẹ iyanu niwaju rẹ̀, eyiti o ti fi ntàn awọn ti o gbà àmi ẹranko na ati awọn ti nforibalẹ fun aworan rẹ̀ jẹ. Awọn mejeji yi li a sọ lãye sinu adagun iná ti nfi sulfuru jò.
Pín
Kà Ifi 19Ifi 19:20 Yoruba Bible (YCE)
A mú ẹranko náà lẹ́rú, pẹlu wolii èké tí ó ń ṣe iṣẹ́ abàmì níwájú rẹ̀, tí ó ti tan àwọn tí wọ́n gba àmì ẹranko náà jẹ, ati àwọn tí wọ́n júbà ère rẹ̀. A wá gbé àwọn mejeeji láàyè, a sọ wọ́n sinu adágún iná tí a fi imí-ọjọ́ dá.
Pín
Kà Ifi 19Ifi 19:20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
A sì mú ẹranko náà, àti wòlíì èké nì pẹ̀lú rẹ̀, tí ó ti ń ṣe iṣẹ́ ìyanu níwájú rẹ̀, èyí tí ó fi ń tan àwọn tí ó gba ààmì ẹranko náà àti àwọn tí ń foríbalẹ̀ fún àwòrán rẹ̀ jẹ. Àwọn méjèèjì yìí ni a sọ láààyè sínú adágún iná tí ń fi sulfuru jó.
Pín
Kà Ifi 19