Ifi 4:1-11
Ifi 4:1-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
LẸHIN nkan wọnyi emi wo, si kiyesi i, ilẹkun kan ṣí silẹ li ọrun: ohùn kini ti mo gbọ bi ohùn ipè ti mba mi sọ̀rọ, ti o wipe, Goke wa ìhin, emi o si fi ohun ti yio hù lẹhin-ọla hàn ọ. Lojukanna mo si wà ninu Ẹmí: si kiyesi i, a tẹ́ itẹ́ kan li ọrun, ẹnikan si joko lori itẹ́ na. Ẹniti o si joko na dabi okuta jaspi ati sardi ni wiwo: oṣumare si ta yi itẹ́ na ká, o dabi okuta smaragdu ni wiwo. Yi itẹ́ na ká si ni itẹ́ mẹrinlelogun: ati lori awọn itẹ́ na mo ri awọn àgba mẹrinlelogun joko, ti a wọ̀ li aṣọ àlà; ade wura si wà li ori wọn. Ati lati ibi itẹ́ na ni mànamána ati ãrá ati ohùn ti jade wá: fitila iná meje si ntàn nibẹ̀ niwaju itẹ́ na, ti iṣe Ẹmi meje ti Ọlọrun. Ati niwaju itẹ́ na si ni okun bi digí, o dabi kristali: li arin itẹ́ na, ati yi itẹ́ na ká, li ẹda alãye mẹrin ti o kún fun oju niwaju ati lẹhin. Ẹda ikini si dabi kiniun, ẹda keji si dabi ọmọ malu, ẹda kẹta si ni oju bi ti enia, ẹda kẹrin si dabi idì ti nfò. Awọn ẹda alaye mẹrin na, ti olukuluku wọn ni iyẹ́ mẹfa, kun fun oju yika ati ninu: nwọn kò si simi li ọsán ati li oru, wipe, Mimọ́, mimọ́, mimọ́, Oluwa Ọlọrun Olodumare, ti o ti wà, ti o si mbẹ, ti o si mbọ̀wá. Nigbati awọn ẹda alãye na ba si fi ogo ati ọlá ati ọpẹ́ fun ẹniti o joko lori itẹ́, ti o mbẹ lãye lai ati lailai, Awọn àgba mẹrinlelogun na a si wolẹ niwaju ẹniti o joko lori itẹ́, nwọn a si tẹriba fun ẹniti mbẹ lãye lai ati lailai, nwọn a si fi ade wọn lelẹ niwaju itẹ́ na, wipe, Oluwa, iwọ li o yẹ lati gbà ogo ati ọlá ati agbara: nitoripe iwọ li o dá ohun gbogbo, ati nitori ifẹ inu rẹ ni nwọn fi wà ti a si dá wọn.
Ifi 4:1-11 Yoruba Bible (YCE)
Lẹ́yìn èyí mo tún rí ìran mìíran. Mo rí ìlẹ̀kùn kan tí ó ṣí sílẹ̀ ní ọ̀run. Mo wá gbọ́ ohùn kan bíi ti àkọ́kọ́. Tí ó dàbí ìgbà tí kàkàkí bá ń dún, tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀. Ó ní, “Gòkè wá níhìn-ín. N óo fi àwọn ohun tí ó níláti ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn èyí hàn ọ́.” Lẹsẹkẹsẹ ni Ẹ̀mí bá gbé mi. Mo bá rí ìtẹ́ kan ní ọ̀run. Ẹnìkan jókòó lórí rẹ̀. Ojú ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ náà dàbí òkúta iyebíye oríṣìí meji. Òṣùmàrè yí ìtẹ́ náà ká, ó ń tan ìmọ́lẹ̀ bí òkúta iyebíye. Àwọn ìtẹ́ mẹrinlelogun ni wọ́n yí ìtẹ́ náà ká. Àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun sì jókòó lórí ìtẹ́ mẹrinlelogun náà. Wọ́n wọ aṣọ funfun, wọ́n dé adé wúrà. Mànàmáná ati ìró ààrá ń jáde láti ara ìtẹ́ tí ó wà láàrin. Ògùṣọ̀ meje tí iná wọn ń jó wà níwájú ìtẹ́ náà. Àwọn yìí ni Ẹ̀mí Ọlọrun meje. Iwájú ìtẹ́ náà dàbí òkun dígí, ó rí bíi yìnyín, ó mọ́ gaara. Àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin kan wà ní ààrin, wọ́n yí ìtẹ́ náà ká. Wọ́n ní ọpọlọpọ ojú níwájú ati lẹ́yìn. Ekinni dàbí kinniun, ekeji dàbí akọ mààlúù, ojú ẹkẹta jọ ti eniyan, ẹkẹrin sì dàbí idì tí ó ń fò. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin náà ní apá mẹfa. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ọpọlọpọ ojú. Wọn kì í sinmi tọ̀sán-tòru, wọ́n ń wí pé, “Mímọ́! Mímọ́! Mímọ́! Oluwa Ọlọrun Olodumare. Ẹni tí ó ti wà, tí ó wà nisinsinyii, tí ó sì ń bọ̀ wá.” Nígbà tí àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin náà bá fi ògo, ọlá ati ìyìn fún ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́, ẹni tí ó wà láàyè lae ati laelae, àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun náà á dojúbolẹ̀ níwájú ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́, wọn a júbà ẹni tí ó wà láàyè lae ati laelae, wọn a fi adé wọn lélẹ̀ níwájú ìtẹ́ náà, wọ́n a máa wí pé, “Oluwa Ọlọrun wa, ìwọ ni ó tọ́ sí láti gba ògo, ati ọlá ati agbára. Nítorí ìwọ ni ó dá ohun gbogbo, ati pé nípa ìfẹ́ rẹ ni wọ́n ṣe wà, nípa rẹ ni a sì ṣe dá wọn.”
Ifi 4:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí èmi wò, sì kíyèsi i, ìlẹ̀kùn kan ṣí sílẹ̀ ní ọ̀run: Ohùn kìn-ín-ní tí mo gbọ́ bí ohùn ìpè tí ń bá mi sọ̀rọ̀, tí ó wí pé, “Gòkè wá níhìn-ín, èmi ó sì fi ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn èyí hàn ọ́.” Lójúkan náà, mo sì wà nínú Ẹ̀mí: sì kíyèsi i, a tẹ́ ìtẹ́ kan ní ọ̀run, ẹnìkan sì jókòó lórí ìtẹ́ náà. Ẹni tí ó sì jókòó náà dàbí òkúta jasperi àti kaneliani lójú. Ni àyíká ìtẹ́ náà ni òṣùmàrè kan wà tí ó dàbí òkúta emeradi lójú. Yí ìtẹ́ náà ká sì ni ìtẹ́ mẹ́rìnlélógún mìíràn; àti lórí àwọn ìtẹ́ náà mo rí àwọn àgbà mẹ́rìnlélógún jókòó, tí a wọ̀ ni aṣọ àlà; adé wúrà sì wà ni orí wọn. Àti láti ibi ìtẹ́ náà ni ìró mọ̀nàmọ́ná àti ohùn àti àrá ti jáde wá: níwájú ìtẹ́ náà ni fìtílà iná méje sì ń tàn, èyí tí ń ṣe Ẹ̀mí méje ti Ọlọ́run. Àti láti ibi ìtẹ́ náà ni òkun bi dígí wà tí o dàbí kristali. Àti yí ìtẹ́ náà ká ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan ni ẹ̀dá alààyè mẹ́rin tí ó kún fún ojú níwájú àti lẹ́yìn wọn. Ẹ̀dá kìn-ín-ní sì dàbí kìnnìún, ẹ̀dá kejì si dàbí ọmọ màlúù, ẹ̀dá kẹta sì ni ojú bi ti ènìyàn, ẹ̀dá kẹrin sì dàbí idì tí ń fò. Àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà, tí olúkúlùkù wọn ni ìyẹ́ mẹ́fà, kún fún ojú yíká ara àti nínú; wọn kò sì sinmi lọ́sàn àti lóru, láti wí pé: “Mímọ́, mímọ́, mímọ́, Olúwa Ọlọ́run Olódùmarè, tí ó ti wà, tí ó sì ń bẹ, tí ó sì ń bọ̀ wá!” Nígbà tí àwọn ẹ̀dá alààyè náà bá sì fi ògo àti ọlá, àti ọpẹ́ fún ẹni tí o jókòó lórí ìtẹ́, tí o ń bẹ láààyè láé àti láéláé. Àwọn àgbà mẹ́rìnlélógún náà yóò sì wólẹ̀ níwájú ẹni tí o jókòó lórí ìtẹ́, wọn yóò sì tẹríba fún ẹni tí ń bẹ láààyè láé àti láéláé, wọn yóò sì fi adé wọn lélẹ̀ níwájú ìtẹ́ náà, wí pé: “Olúwa àti Ọlọ́run, ìwọ ni o yẹ, láti gba ògo àti ọlá àti agbára: nítorí pé ìwọ ni o dá ohun gbogbo, àti nítorí ìfẹ́ inú rẹ̀ ni wọn fi wà tí a sì dá wọn.”