Ifi 6:12-13
Ifi 6:12-13 Yoruba Bible (YCE)
Mo rí i nígbà tí ó tú èdìdì kẹfa pé ilẹ̀ mì tìtì. Oòrùn ṣókùnkùn, ó dàbí aṣọ dúdú. Òṣùpá wá dàbí ẹ̀jẹ̀. Àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run já bọ́ sílẹ̀, bí ìgbà tí èso ọ̀pọ̀tọ́ bá já bọ́ lára igi rẹ̀ nígbà tí afẹ́fẹ́ líle bá fẹ́ lù ú.
Pín
Kà Ifi 6Ifi 6:12-13 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati o si ṣí èdidi kẹfa mo si ri, si kiyesi i, ìṣẹlẹ nla kan ṣẹ̀; õrùn si dudu bi aṣọ-ọfọ onirun, oṣupa si dabi ẹ̀jẹ; Awọn irawọ oju ọrun si ṣubu silẹ gẹgẹ bi igi ọpọtọ iti rẹ̀ àigbó eso rẹ̀ dànu, nigbati ẹfũfu nla ba mì i.
Pín
Kà Ifi 6Ifi 6:12-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí ó sì ṣí èdìdì kẹfà mo sì rí i, sì kíyèsi i, ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá kan ṣẹ̀; oòrùn sì dúdú bí aṣọ ọ̀fọ̀ onírun, òṣùpá sì dàbí ẹ̀jẹ̀; àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run sì ṣubú sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí igi ọ̀pọ̀tọ́ tí ń rẹ̀ àìgbó èso rẹ̀ dànù, nígbà tí ẹ̀fúùfù ńlá bá mì í.
Pín
Kà Ifi 6