Ifi 6:5-6
Ifi 6:5-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati o si ṣí èdidi kẹta, mo gbọ́ ohùn ẹda alãye kẹta nwipe, Wá, wò o. Mo si wò, si kiyesi i, ẹṣin dúdu kan; ẹniti o joko lori rẹ̀ ni oṣuwọn awẹ́ meji li ọwọ́ rẹ̀. Mo si gbọ́ bi ẹnipe ohùn kan li arin awọn ẹda alãye mẹrẹrin nì ti nwipe, Oṣuwọn alikama kan fun owo idẹ kan, ati oṣuwọn ọkà barle mẹta fun owo idẹ kan; si kiyesi i, ki o má si ṣe pa oróro ati ọti-waini lara.
Ifi 6:5-6 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí ó tú èdìdì kẹta, mo gbọ́ tí ẹ̀dá alààyè kẹta ní, “Wá!” Mo rí ẹṣin dúdú kan. Ẹni tí ó gùn ún mú ìwọ̀n kan lọ́wọ́. Mo wá gbọ́ nǹkankan tí ó dàbí ohùn láàrin àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin náà, ó ní, “Páànù ọkà bàbà kan fún owó fadaka kan. Páànù ọkà baali mẹta fún owó fadaka kan. Ṣugbọn o kò gbọdọ̀ fọwọ́ kan igi olifi ati ọtí waini.”
Ifi 6:5-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí ó sì di èdìdì kẹta, mo gbọ́ ohùn ẹ̀dá alààyè kẹta wí pé, “Wá wò ó”. Mo sì wò ó, sì kíyèsi i, ẹṣin dúdú kan; ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀ ní ìwọ̀n aláwẹ́ méjì ní ọwọ́ rẹ̀. Mo sì gbọ́ bí ẹni pé ohùn kan ní àárín àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rẹ̀ẹ̀rin nì ti ń wí pé, òṣùwọ̀n alikama kan fún owó idẹ kan, àti òṣùwọ̀n ọkà barle mẹ́ta fún owó idẹ kan, sì kíyèsi i, kí ó má sì ṣe pa òróró àti ọtí wáìnì lára.