Ifi 9:20-21
Ifi 9:20-21 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn awọn enia iyokù, ti a kò si ti ipa iyọnu wọnyi pa, kò si ronupiwada iṣẹ́ ọwọ́ wọn, ki nwọn ki o máṣe sìn awọn ẹmi èṣu, ati ere wura, ati ti fadaka, ati ti idẹ, ati ti okuta, ati ti igi mọ́, awọn ti kò le riran, tabi ki nwọn gbọran, tabi ki nwọn rìn: Bẹ̃ni nwọn kò ronupiwada enia pipa wọn, tabi oṣó wọn, tabi àgbere wọn, tabi olè wọn.
Ifi 9:20-21 Yoruba Bible (YCE)
Àwọn eniyan tí ó kù, tí wọn kò kú ninu àjàkálẹ̀ àrùn yìí kò ronupiwada. Wọn kò kọ iṣẹ́ ọwọ́ wọn tí wọn ń bọ sílẹ̀. Ṣugbọn wọ́n tún ń sin àwọn ẹ̀mí burúkú, ati oriṣa wúrà, ti fadaka, ti idẹ, ti òkúta, ati ti igi. Àwọn oriṣa tí kò lè ríran, wọn kò lè gbọ́ràn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò lè rìn. Àwọn eniyan náà kò ronupiwada kúrò ninu ìwà ìpànìyàn, ìwà oṣó, ìwà àgbèrè ati ìwà olè wọn.
Ifi 9:20-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn ìyókù tí a kò sì ti ipa ìyọnu wọ̀nyí pa, kò sì ronúpìwàdà iṣẹ́ ọwọ́ wọn, kí wọn má ṣe sin àwọn ẹ̀mí èṣù àti ère wúrà, àti ti fàdákà, àti ti idẹ, àti òkúta, àti ti igi mọ́: àwọn tí kò lè ríran, tàbí kí wọn gbọ́rọ̀, tàbí kí wọn rìn: Bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ronúpìwàdà ìwà ìpànìyàn wọn, tàbí oṣó wọn tàbí àgbèrè wọn, tàbí olè wọn.