Ifi 9:3-4
Ifi 9:3-4 Yoruba Bible (YCE)
Àwọn eṣú ti tú jáde láti inú èéfín náà, wọ́n lọ sí orí ilẹ̀ ayé. A fún wọn ní agbára bíi ti àkeekèé ayé. A sọ fún wọn pé kí wọ́n má ṣe ohunkohun sí koríko orí ilẹ̀ tabi sí ewébẹ̀ tabi sí igi kan. Gbogbo àwọn eniyan tí kò bá ní èdìdì Ọlọrun ní iwájú wọn nìkan ni kí wọ́n ṣe léṣe.
Ifi 9:3-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẽṣú si jade ti inu ẹ̃fin na wá sori ilẹ: a si fi agbara fun wọn bi akẽkẽ ilẹ ti li agbara. A si sọ fun wọn pe ki nwọn ki o máṣe pa koriko ilẹ lara, tabi ohun tutù kan, tabi igikigi kan; bikoṣe awọn enia ti kò ni èdidi Ọlọrun ni iwaju wọn.
Ifi 9:3-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àwọn eṣú sì jáde ti inú èéfín náà wá sórí ilẹ̀: a sì fi agbára fún wọn gẹ́gẹ́ bí agbára àkéekèe ilẹ̀. A sì fún wọn pé ki wọn má ṣe pa koríko ilẹ̀ lára tàbí ohun tútù kan, tàbí igikígi kan; bí kò ṣe àwọn ènìyàn tí kò ni èdìdì Ọlọ́run ní iwájú wọn.