Ṣe àfiwé gbogbo èyà
Rom 2:12-13YBCV(Bibeli Mimọ)
Nitori iye awọn ti o ṣẹ̀ li ailofin, nwọn ó si ṣegbé lailofin: ati iye awọn ti o ṣẹ̀ labẹ ofin, awọn li a o fi ofin dalẹjọ; Nitori kì iṣe awọn olugbọ ofin li alare lọdọ Ọlọrun, ṣugbọn awọn oluṣe ofin li a o dalare.
Pín
Rom 2YBCVRom 2:12-13BMYO(Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo àwọn tí ó ṣẹ̀ ní àìlófin wọn ó sì ṣègbé láìlófin, àti iye àwọn tí ó ṣẹ̀ lábẹ́ òfin, àwọn ni a ó fi òfin dá lẹ́jọ́. Nítorí kì í ṣe àwọn olùgbọ́ òfin ni ẹni ìdáláre lọ́dọ̀ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n àwọn olùṣe òfin ni a ó dá láre.
Pín
Rom 2BMYORom 2:12-13YCE(Yoruba Bible)
Gbogbo àwọn tí wọ́n bá dẹ́ṣẹ̀ láì lófin, láì lófin náà ni wọn yóo kú. Gbogbo àwọn tí wọ́n mọ Òfin, tí wọ́n sì dẹ́ṣẹ̀, òfin náà ni a óo fi ṣe ìdájọ́ wọn. Kì í ṣe àwọn tí wọ́n gbọ́ ohun tí Òfin sọ ni Ọlọrun ń dá láre, àwọn tí wọn ń ṣe ohun tí Òfin sọ ni.
Pín
Rom 2YCE