Rom 5:1-2
Rom 5:1-2 Bibeli Mimọ (YBCV)
NJẸ bi a si ti nda wa lare nipa igbagbọ́, awa ni alafia lọdọ Ọlọrun nipa Oluwa wa Jesu Kristi: Nipasẹ ẹniti awa si ti ri ọ̀na gbà nipa igbagbọ́ si inu ore-ọfẹ yi ninu eyi ti awa gbé duro, awa si nyọ̀ ni ireti ogo Ọlọrun.
Pín
Kà Rom 5Rom 5:1-2 Yoruba Bible (YCE)
Níwọ̀n ìgbà tí a ti dá wa láre nítorí pé a gba Ọlọrun gbọ́, kò sí ìjà mọ́ láàrin àwa ati Ọlọrun: Jesu Kristi Oluwa wa ti parí ìjà. Ọpẹ́lọpẹ́ rẹ̀ ni a fi rí ọ̀nà gbà dé ipò oore-ọ̀fẹ́ tí a wà ninu rẹ̀ yìí. A wá ń yọ̀ ninu ògo Ọlọrun tí à ń retí.
Pín
Kà Rom 5Rom 5:1-2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí náà, níwọ̀n ìgbà tí a ti dá wa láre nípa ìgbàgbọ́, àwa ní àlàáfíà lọ́dọ̀ Ọlọ́run nípasẹ̀ Olúwa wa Jesu Kristi. Nípasẹ̀ ẹni tí àwa sì ti rí ọ̀nà gbà nípa ìgbàgbọ́ sí inú oore-ọ̀fẹ́ yìí nínú èyí tí àwa gbé dúró. Àwa sì ń yọ̀ nínú ìrètí ògo Ọlọ́run.
Pín
Kà Rom 5