Rom 8:1-10
Rom 8:1-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
NJẸ ẹbi kò si nisisiyi fun awọn ti o wà ninu Kristi Jesu, awọn ti kò rìn nipa ti ara, bikoṣe nipa ti Ẹmí. Nitori ofin Ẹmí ìye ninu Kristi Jesu ti sọ mi di omnira lọwọ ofin ẹ̀ṣẹ ati ti ikú. Nitori ohun ti ofin kò le ṣe, bi o ti jẹ alailera nitori ara, Ọlọrun rán Ọmọ on tikararẹ̀ li aworan ara ẹ̀ṣẹ, ati bi ẹbọ fun ẹ̀ṣẹ, o si da ẹ̀ṣẹ lẹbi ninu ara: Ki a le mu ododo ofin ṣẹ ninu awa, ti kò rin nipa ti ara, bikoṣe nipa ti Ẹmí. Nitori awọn ti o wà nipa ti ara, nwọn a mã ro ohun ti ara; ṣugbọn awọn ti o wà nipa ti Ẹmí, nwọn a mã ro ohun ti Ẹmí. Nitori ero ti ara ikú ni; ṣugbọn ero ti Ẹmí ni iye ati alafia: Nitori ero ti ara ọtá ni si Ọlọrun: nitori ki itẹriba fun ofin Ọlọrun, on kò tilẹ le ṣe e. Bẹ̃li awọn ti o wà ninu ti ara, kò le wù Ọlọrun. Ṣugbọn ẹnyin kò si ninu ti ara, bikoṣe ninu ti Ẹmí, biobaṣepe Ẹmí Ọlọrun ngbe inu nyin. Ṣugbọn bi ẹnikẹni kò ba ni Ẹmí Kristi, on kò si ninu ẹni tirẹ̀. Bi Kristi ba si wà ninu nyin, ara jẹ okú nitori ẹ̀ṣẹ: ṣugbọn ẹmí jẹ iyè nitori ododo.
Rom 8:1-10 Yoruba Bible (YCE)
Nisinsinyii, kò sí ìdálẹ́bi kan mọ́ fún àwọn tí ó wà ní ìṣọ̀kan pẹlu Kristi Jesu. Ìdí ni pé, agbára Ẹ̀mí, tí ó ń fi ìyè fún àwọn tí ń bá Kristi gbé, ti dá mi nídè kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ ati kúrò lábẹ́ àṣẹ ikú. Èyí jẹ́ nǹkan tí kò ṣe é ṣe lábẹ́ Òfin, nítorí eniyan kò lè ṣàì dẹ́ṣẹ̀. Ṣugbọn Ọlọrun ti ṣe é, nígbà tí ó dá ẹ̀bi ikú fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ń bẹ ninu ẹ̀yà ara eniyan. Àní sẹ́, Ọlọrun rán Ọmọ rẹ̀ wá gẹ́gẹ́ bí eniyan ẹlẹ́ṣẹ̀ láti pa ẹ̀ṣẹ̀ rẹ́. Ọlọrun ṣe èyí kí á lè tẹ̀lé ìlànà Òfin ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, àní àwa tí ìhùwàsí wa kì í ṣe bíi tí ẹni tí ẹran-ara ń lò ṣugbọn bí àwọn ẹni tí Ẹ̀mí ń darí. Nítorí àwọn tí ó ń hùwà gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ẹran- ara ń lò a máa lépa ìtẹ́lọ́rùn fún ẹran-ara; ṣugbọn àwọn tí Ẹ̀mí ń darí a máa lépa àwọn nǹkan ti Ẹ̀mí. Lílépa àwọn nǹkan ti ẹran-ara nìkan a máa yọrí sí ikú, ṣugbọn lílépa àwọn nǹkan ti Ẹ̀mí a máa fúnni ní ìyè ati alaafia. Ìdí nìyí tí àwọn tí ń lépa nǹkan ti ẹran-ara nìkan fi jẹ́ ọ̀tá Ọlọrun, nítorí àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ kò lè fara wọn sábẹ́ àṣẹ Ọlọrun; wọn kò tilẹ̀ lè ṣe é rárá ni. Àwọn tí ń ṣe ìfẹ́ ẹran-ara wọn kò lè sin Ọlọrun. Ṣugbọn ní tiyín, ẹ kò hùwà gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ẹran-ara ń darí mọ́; Ẹ̀mí ló ń ṣamọ̀nà yín, bí Ẹ̀mí Ọlọrun bá ń gbé inú yín nítòótọ́. Nítorí pé ẹnikẹ́ni tí kò bá ní Ẹ̀mí Kristi ninu rẹ̀, kì í ṣe ti Kristi. Ṣugbọn bí Kristi bá ń gbé inú yín, bí ara yín yóo tilẹ̀ kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀, sibẹ ẹ̀mí yín yóo wà láàyè nítorí pé Ọlọrun ti da yín láre.
Rom 8:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí náà, kò sí ìdálẹ́bi nísinsin yìí fún àwọn tí ó wà nínú Kristi Jesu, àwọn tí kò rìn nípa ti ara, bí kò ṣe nípa ti Ẹ̀mí. Nítorí nípasẹ̀ òfin ti ẹ̀mí ìyè nínú Kristi Jesu ti sọ mí di òmìnira kúrò lọ́wọ́ òfin ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Nítorí ohun tí òfin kò lè ṣe, bí ó ti jẹ aláìlera nítorí ara, Ọlọ́run rán ọmọ òun tìkára rẹ̀ ní àwòrán ara ẹ̀ṣẹ̀, ó sì di ẹ̀ṣẹ̀; àti bi ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀, ó sì dá ẹ̀ṣẹ̀ lẹ́bi nínú ara, kí a lè mú òdodo òfin ṣẹ, nínú wa, nítorí tí àwa yé gẹ́gẹ́ bí ohun ti ara, bí kò ṣe gẹ́gẹ́ bí ohun ti Ẹ̀mí. Àwọn tí ń gbe nípa ti ara, wọn a máa ronú ohun ti ara; ṣùgbọ́n àwọn ti ń gbe nípa ti Ẹ̀mí, wọn a máa ronú ohun ti Ẹ̀mí. Nítorí èrò ti ara ikú ni; ṣùgbọ́n èrò ti ẹ̀mí ni ìyè àti àlàáfíà. Nítorí èrò ti ara ọ̀tá ni sí Ọlọ́run, nítorí kì í tẹríba fún òfin Ọlọ́run, òun kò tilẹ̀ le ṣe e. Ìdí nìyìí tí àwọn tí ó wà lábẹ́ àkóso ara ẹ̀ṣẹ̀, kò le è tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn. Ṣùgbọ́n ẹyin kò sí nínú ti ara, bí kò ṣe nínú ti Ẹ̀mí, bí ó bá ṣe pé Ẹ̀mí Ọlọ́run ń gbé inú yín, Ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni kò bá ní Ẹ̀mí Kristi, òun kò sí nínú ẹni tirẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Kristi ń gbé inú yín síbẹ̀síbẹ̀, ara yín jẹ́ òkú nítorí ẹ̀ṣẹ̀; ṣùgbọ́n ẹ̀mí mímọ́ tí ń gbé inú yín yóò fún yín ní ìyè, nítorí ó ti fún un yín ní òdodo.