Tit 2:7-8
Tit 2:7-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ninu ohun gbogbo mã fi ara rẹ hàn li apẹrẹ iṣẹ rere: ninu ẹkọ́ mã fi aiṣebajẹ hàn, ìwa àgba, Ọ̀rọ ti o yè kõro, ti a kò le da lẹbi; ki oju ki o tì ẹniti o nṣòdi, li aini ohun buburu kan lati wi si wa.
Pín
Kà Tit 2Tit 2:7-8 Yoruba Bible (YCE)
Kí o ṣe ara rẹ ní àpẹẹrẹ rere ní gbogbo ọ̀nà. Ninu ẹ̀kọ́ tí ò ń kọ́ àwọn eniyan, kí wọn rí òtítọ́ ninu rẹ, kí wọn sì rí ìwà àgbà lọ́wọ́ rẹ. Kí gbolohun ẹnu rẹ jẹ́ ti ọmọlúwàbí, tí ẹnìkan kò ní lè fi bá ọ wí. Èyí yóo mú ìtìjú bá ẹni tí ó bá fẹ́ ṣe alátakò nígbà tí kò bá rí ohun burúkú kan sọ nípa wa.
Pín
Kà Tit 2