Sek 8:16-17 - Compare All Versions

Sek 8:16-17 YBCV (Bibeli Mimọ)

Wọnyi ni nkan ti ẹnyin o ṣe: Ẹ sọ̀rọ otitọ, olukuluku si ẹnikeji rẹ̀; ṣe idajọ tõtọ ati alafia ni bodè nyin wọnni. Ẹ máṣe jẹ ki ẹnikan ki o rò ibi li ọkàn rẹ̀ si ẹnikeji rẹ̀; ẹ má fẹ ibura eke: nitori gbogbo wọnyi ni mo korira, li Oluwa wi.

Sek 8:16-17 YCE (Yoruba Bible)

Àwọn nǹkan tí ó yẹ kí ẹ máa ṣe nìyí: ẹ máa bá ara yín sọ òtítọ́, kí ẹ sì máa ṣe ìdájọ́ òtítọ́ nílé ẹjọ́; èyí ni yóo máa mú alaafia wá. Ẹ má máa gbèrò ibi sí ara yín, ẹ má sì fẹ́ràn ìbúra èké, nítorí gbogbo nǹkan wọnyi ni mo kórìíra.”

Sek 8:16-17 BMYO (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)

Wọ̀nyí ni nǹkan tí ẹ̀yin ó ṣe: ki olúkúlùkù yín kí ó máa ba ọmọnìkejì rẹ̀ sọ òtítọ́; ṣe ìdájọ́ tòótọ́ àti àlàáfíà ní àwọn ibodè yín. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnìkan ro ibi ni ọkàn rẹ̀ sí ẹnìkejì rẹ̀; ẹ má fẹ́ ìbúra èké; nítorí gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni mo kórìíra,” ni OLúWA wí.