JOHANU 14:1-3
Ẹ maṣe jẹ ki ọkàn nyin dàru: ẹ gbà Ọlọrun gbọ́, ẹ gbà mi gbọ́ pẹlu. Ninu ile Baba mi ọ̀pọlọpọ ibugbe li o wà: ibamáṣe bẹ̃, emi iba ti sọ fun nyin. Nitori emi nlọ ipèse àye silẹ fun nyin. Bi mo ba si lọ ipèse àye silẹ fun nyin, emi o tún pada wá, emi o si mu nyin lọ sọdọ emi tikarami; pe nibiti emi gbé wà, ki ẹnyin le wà nibẹ pẹlu.
Joh 14:1-3