1
ÀWỌN ỌBA KEJI 2:9
Yoruba Bible
Níbẹ̀ ni Elija ti bèèrè lọ́wọ́ Eliṣa pé, “Kí ni o fẹ́ kí n ṣe fún ọ kí á tó gbé mi kúrò lọ́dọ̀ rẹ.” Eliṣa sì dáhùn pé, “Mo bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí ìlọ́po meji agbára rẹ bà lé mi.”
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí ÀWỌN ỌBA KEJI 2:9
2
ÀWỌN ỌBA KEJI 2:11
Bí wọ́n ti ń lọ tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀, lójijì kẹ̀kẹ́-ogun iná ati ẹṣin iná gba ààrin wọn kọjá, Elija sì bá ààjà gòkè lọ sí ọ̀run.
Ṣàwárí ÀWỌN ỌBA KEJI 2:11
3
ÀWỌN ỌBA KEJI 2:10
Elija dáhùn pé, “Ohun tí o bèèrè yìí ṣòro, ṣugbọn bí o bá rí mi nígbà tí wọ́n bá ń gbé mi lọ, o óo rí ohun tí o bèèrè gbà. Ṣugbọn bí o kò bá rí mi, o kò ní rí i gbà.”
Ṣàwárí ÀWỌN ỌBA KEJI 2:10
4
ÀWỌN ỌBA KEJI 2:14
Ó fi aṣọ àwọ̀lékè tí ó já bọ́ sílẹ̀ lára Elija lu odò, ó sì kígbe pé, “Níbo ni OLUWA Ọlọrun Elija wà?” Lẹ́yìn náà odò pín sí meji, Eliṣa bá kọjá sí òdìkejì.
Ṣàwárí ÀWỌN ỌBA KEJI 2:14
5
ÀWỌN ỌBA KEJI 2:12
Bí Eliṣa ti rí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, ó kígbe pe Elija, ó ní, “Baba mi, baba mi, kẹ̀kẹ́-ogun Israẹli ati àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀.” Kò rí Elija mọ́, ó bá fa aṣọ rẹ̀ ya sí meji láti fi ìbànújẹ́ rẹ̀ hàn.
Ṣàwárí ÀWỌN ỌBA KEJI 2:12
6
ÀWỌN ỌBA KEJI 2:8
Elija bọ́ aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀, ó fi lu odò náà, odò sì pín sí meji títí tí Elija ati Eliṣa fi kọjá sí òdìkejì odò lórí ìyàngbẹ ilẹ̀.
Ṣàwárí ÀWỌN ỌBA KEJI 2:8
7
ÀWỌN ỌBA KEJI 2:1
Nígbà tí àkókò tó fún OLUWA láti fi ààjà gbé Elija lọ sí ọ̀run, Elija ati Eliṣa kúrò ní Giligali.
Ṣàwárí ÀWỌN ỌBA KEJI 2:1
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò