1
SAMUẸLI KEJI 18:33
Yoruba Bible
Ìbànújẹ́ ńlá dé bá ọba, ó bá gun òkè lọ sinu yàrá tí ó wà lókè ẹnu ọ̀nà ibodè, ó sì sọkún. Bí ó ti ń lọ, bẹ́ẹ̀ ni ó ń ké pé, “Ha! Ọmọ mi! Absalomu, ọmọ mi! Absalomu, ọmọ mi! Ọmọ mi! Kì bá ṣe pé ó ṣeéṣe ni, kí n kú dípò rẹ, Absalomu, ọmọ mi, ọmọ mi!”
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí SAMUẸLI KEJI 18:33
2
SAMUẸLI KEJI 18:9-10
Lójijì, Absalomu já sí ààrin àwọn ọmọ ogun Dafidi. Ìbaaka ni Absalomu gùn. Ìbaaka yìí gba abẹ́ ẹ̀ka igi Oaku ńlá kan, ẹ̀ka igi yìí sì dí tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi kọ́ Absalomu ní irun orí, Ìbaaka yọ lọ lábẹ́ rẹ̀, Absalomu sì ń rọ̀ dirodiro nítorí pé ẹsẹ̀ rẹ̀ kò tólẹ̀. Ọ̀kan ninu àwọn ọmọ ogun Dafidi rí i, ó bá lọ sọ fún Joabu pé òun rí Absalomu tí ó ń rọ̀ lórí igi Oaku.
Ṣàwárí SAMUẸLI KEJI 18:9-10
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò