Ó ní,
‘Lọ sọ fún àwọn eniyan yìí pé:
Ẹ óo fetí yín gbọ́, ṣugbọn kò ní ye yín;
Ẹ óo wò ó títí, ṣugbọn ẹ kò ní mọ̀ ọ́n.
Nítorí ọkàn àwọn eniyan yìí kò ṣí;
wọ́n ti di alágbọ̀ọ́ya,
wọ́n ti dijú.
Bí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀,
wọn ìbá fi ojú wọn ríran,
wọn ìbá fetí gbọ́ràn,
òye ìbá yé wọn,
wọn ìbá yipada;
èmi ìbá sì wò wọ́n sàn.’