1
ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 12:13
Yoruba Bible
Kókó gbogbo ọ̀rọ̀ náà ni ohun tí a ti gbọ́ tẹ́lẹ̀ pé, bẹ̀rù Ọlọrun, kí o sì pa òfin rẹ̀ mọ́, nítorí èyí nìkan ni iṣẹ́ ọmọ eniyan.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 12:13
2
ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 12:14
Nítorí Ọlọrun yóo mú gbogbo nǹkan tí eniyan bá ṣe wá sí ìdájọ́, ati gbogbo nǹkan àṣírí, ìbáà ṣe rere tabi burúkú.
Ṣàwárí ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 12:14
3
ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 12:1-2
Ranti ẹlẹ́dàá rẹ ní ìgbà èwe rẹ, kí ọjọ́ ibi tó dé, kí ọjọ́ ogbó rẹ tó súnmọ́ etílé, nígbà tí o óo wí pé, “N kò ní inú dídùn ninu wọn.” Kí oòrùn ati ìmọ́lẹ̀ ati òṣùpá ati ìràwọ̀ tó ṣókùnkùn, kí ìkùukùu tó pada lẹ́yìn òjò
Ṣàwárí ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 12:1-2
4
ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 12:6-7
kí ẹ̀wọ̀n fadaka tó já, kí àwo wúrà tó fọ́; kí ìkòkò tó fọ́ níbi orísun omi, kí okùn ìfami tó já létí kànga; kí erùpẹ̀ tó pada sí ilẹ̀ tí ó wà tẹ́lẹ̀, kí ẹ̀mí tó pada tọ Ọlọrun tí ó fúnni lọ.
Ṣàwárí ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 12:6-7
5
ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 12:8
Asán ninu asán, ọ̀jọ̀gbọ́n ní, asán ni gbogbo rẹ̀.
Ṣàwárí ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 12:8
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò