1
ISIKIẸLI 33:11
Yoruba Bible
YCE
Wí fún wọn pé èmi OLUWA ní, mo fi ara mi búra pé inú mi kò dùn sí ikú eniyan burúkú, ohun tí mo fẹ́ ni pé kí ó yipada kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, kí ó sì yè. Ẹ yipada! Ẹ yipada kúrò ninu iṣẹ́ ibi yín, ẹ̀yin ọmọ Israẹli, kí ló dé tí ẹ fi fẹ́ kú?
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí ISIKIẸLI 33:11
2
ISIKIẸLI 33:7
“Ọmọ eniyan, ìwọ ni mo yàn ní olùṣọ́ fún ilé Israẹli; nígbàkúùgbà tí o bá gbọ́ ọ̀rọ̀ kan lẹ́nu mi, o níláti bá mi kìlọ̀ fún wọn.
Ṣàwárí ISIKIẸLI 33:7
3
ISIKIẸLI 33:9
Ṣugbọn bí ìwọ bá kìlọ̀ fún eniyan burúkú pé kí ó yipada kúrò ní ọ̀nà ibi rẹ̀, tí kò sì yipada, yóo kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ṣugbọn ìwọ ti gba ẹ̀mí ara tìrẹ là.
Ṣàwárí ISIKIẸLI 33:9
4
ISIKIẸLI 33:6
Ṣugbọn bí olùṣọ́ bá rí i pé ogun ń bọ̀, tí kò bá fọn fèrè kí ó kìlọ̀ fún àwọn eniyan; bí ogun bá pa ẹnikẹ́ni ninu wọn, ẹni tí ogun pa yóo kú ninu ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ṣugbọn èmi OLUWA óo bèèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ olùṣọ́ náà.
Ṣàwárí ISIKIẸLI 33:6
5
ISIKIẸLI 33:5
Ó gbọ́ ìró fèrè ṣugbọn kò bìkítà, nítorí náà orí ara rẹ̀ ni ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yóo wà. Bí ó bá gbọ́ ìkìlọ̀ ni, kì bá gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là.
Ṣàwárí ISIKIẸLI 33:5