1
GALATIA 6:9
Yoruba Bible
Kí á má ṣe jẹ́ kí ó sú wa láti ṣe rere, nítorí nígbà tí ó bá yá, a óo kórè rẹ̀, bí a kò bá jẹ́ kí ó rẹ̀ wá.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí GALATIA 6:9
2
GALATIA 6:10
Nítorí náà, bí a bá ti ń rí ààyè kí á máa ṣe oore fún gbogbo eniyan, pàápàá fún àwọn ìdílé onigbagbọ.
Ṣàwárí GALATIA 6:10
3
GALATIA 6:2
Ẹ máa ran ara yín lẹ́rù, bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe mú òfin Kristi ṣẹ.
Ṣàwárí GALATIA 6:2
4
GALATIA 6:7
Ẹ má tan ara yín jẹ: eniyan kò lè mú Ọlọrun lọ́bọ. Ohunkohun tí eniyan bá gbìn ni yóo ká.
Ṣàwárí GALATIA 6:7
5
GALATIA 6:8
Nítorí àwọn tí ó bá ń gbin nǹkan ti Ẹ̀mí yóo ká àwọn nǹkan ti Ẹ̀mí, tíí ṣe ìyè ainipẹkun.
Ṣàwárí GALATIA 6:8
6
GALATIA 6:1
Ará, bí ẹ bá ká ẹ̀ṣẹ̀ mọ́ ẹnìkan lọ́wọ́, kí ẹ̀yin tí ẹ̀mí ń darí ìgbé-ayé yín mú irú ẹni bẹ́ẹ̀ bọ̀ sípò pẹlu ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀. Ṣọ́ra rẹ, kí á má baà dán ìwọ náà wò.
Ṣàwárí GALATIA 6:1
7
GALATIA 6:3-5
Nítorí bí ẹnìkan bá rò pé òun jẹ́ pataki nígbà tí kò jẹ́ nǹkan, ara rẹ̀ ni ó ń tàn jẹ. Kí olukuluku yẹ iṣẹ́ ara rẹ̀ wò, nígbà náà yóo lè ṣògo lórí iṣẹ́ tirẹ̀, kì í ṣe pé kí ó máa fi iṣẹ́ tirẹ̀ wé ti ẹlòmíràn. Nítorí olukuluku gbọdọ̀ ru ẹrù tirẹ̀.
Ṣàwárí GALATIA 6:3-5
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò