1
AISAYA 62:4
Yoruba Bible
A kò ní pè ọ́ ní “Ẹni-tí-a-kọ̀-sílẹ̀” mọ́, bẹ́ẹ̀ ni a kò ní pe ilẹ̀ rẹ ní “Ahoro” mọ́, “Ẹni-OLUWA-fẹ́” ni a óo máa pè ọ́, a óo máa pe ilẹ̀ rẹ ní “Ẹni-a-gbé-níyàwó.” Nítorí pé OLUWA nífẹ̀ẹ́ rẹ, ilẹ̀ rẹ yóo sì dàbí iyawo lójú rẹ̀.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí AISAYA 62:4
2
AISAYA 62:6-7
Jerusalẹmu, mo ti fi àwọn aṣọ́de sí orí odi rẹ; lojoojumọ, tọ̀sán-tòru, wọn kò gbọdọ̀ panumọ́. Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń rán OLUWA létí, ẹ má dákẹ́. Ẹ má jẹ́ kí ó sinmi, títí yóo fi fi ìdí Jerusalẹmu múlẹ̀, títí yóo fi sọ ọ́ di ìlú ìyìn láàrin gbogbo ayé.
Ṣàwárí AISAYA 62:6-7
3
AISAYA 62:3
O óo jẹ́ adé ẹwà lọ́wọ́ OLUWA, ati fìlà oyè lọ́wọ́ Ọlọrun rẹ.
Ṣàwárí AISAYA 62:3
4
AISAYA 62:5
Bí ọdọmọkunrin tií nífẹ̀ẹ́ wundia, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọkunrin rẹ yóo nífẹ̀ẹ́ rẹ. Bí inú ọkọ iyawo tuntun tíí dùn nítorí iyawo rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni inú Ọlọrun rẹ yóo dùn nítorí rẹ.
Ṣàwárí AISAYA 62:5
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò