Ẹ̀mí OLUWA, Ọlọrun tí bà lé mi,
nítorí ó ti fi àmì òróró yàn mí,
láti mú ìròyìn ayọ̀ wá fún àwọn tí a ni lára.
Ó rán mi pé kí n máa tu àwọn tí ó ní ìbànújẹ́ ninu,
kí n máa kéde ìdásílẹ̀ fún àwọn tí ó wà ní ìgbèkùn,
kí n sì máa ṣí ìlẹ̀kùn ọgbà ẹ̀wọ̀n sílẹ̀ fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n.
Ó ní kí n máa kéde ọdún ojurere OLUWA,
ati ọjọ́ ẹ̀san Ọlọrun wa;
kí n sì máa tu àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ ninu.
Ó ní kí n máa fún àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ ní Sioni,
ní inú dídùn dípò ìkáàánú,
kí n fún wọn ní ayọ̀ dípò ìbànújẹ́,
kí n jẹ́ kí wọn máa kọrin ìyìn dípò ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn,
kí á lè máa pè wọ́n ní igi òdodo,
tí OLUWA gbìn,
kí á lè máa yìn ín lógo.