AISAYA 61
61
Ìròyìn Ayọ̀ Ìdáǹdè
1Ẹ̀mí OLUWA, Ọlọrun tí bà lé mi,#Mat 11:5; Luk 7:22
nítorí ó ti fi àmì òróró yàn mí,
láti mú ìròyìn ayọ̀ wá fún àwọn tí a ni lára.
Ó rán mi pé kí n máa tu àwọn tí ó ní ìbànújẹ́ ninu,
kí n máa kéde ìdásílẹ̀ fún àwọn tí ó wà ní ìgbèkùn,
kí n sì máa ṣí ìlẹ̀kùn ọgbà ẹ̀wọ̀n sílẹ̀ fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n.
2Ó ní kí n máa kéde ọdún ojurere OLUWA,#Luk 4:18-19; Mat 5:4
ati ọjọ́ ẹ̀san Ọlọrun wa;
kí n sì máa tu àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ ninu.
3Ó ní kí n máa fún àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ ní Sioni,
ní inú dídùn dípò ìkáàánú,
kí n fún wọn ní ayọ̀ dípò ìbànújẹ́,
kí n jẹ́ kí wọn máa kọrin ìyìn dípò ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn,
kí á lè máa pè wọ́n ní igi òdodo,
tí OLUWA gbìn,
kí á lè máa yìn ín lógo.
4Wọn óo tún àlàpà ahoro àtijọ́ kọ́,
wọn óo tún gbogbo ilé tí ó ti wó lulẹ̀ kọ́,
wọn óo sì tún ìlú tí a ti parun láti ọdún gbọọrọ kọ́.
5Àwọn àjèjì ni yóo máa ba yín bọ́ agbo ẹran yín,
àwọn ni yóo sì máa ṣe alágbàṣe ninu ọgbà àjàrà yín;
6ṣugbọn a óo máa pe ẹ̀yin ní alufaa OLUWA,
àwọn eniyan yóo sì máa sọ̀rọ̀ yín bí iranṣẹ Ọlọrun wa.
Ẹ̀yin ni ẹ óo máa jẹ ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn,
ọrọ̀ wọn ni ẹ óo sì máa fi ṣògo.
7Dípò ìtìjú ìpín tiyín yóo jẹ́ meji,
dípò àbùkù ẹ óo láyọ̀ ninu ìpín tí ó kàn yín.
Ìlọ́po meji ni ìpín yín yóo jẹ́ ninu ilẹ̀ yín,
ayọ̀ ayérayé yóo sì jẹ́ tiyín.
8OLUWA ní,
“Nítorí pé mo fẹ́ ẹ̀tọ́,
mo sì kórìíra ìfipá jalè ati ohun tí kò tọ́.
Dájúdájú n óo san ẹ̀san fún wọn,
n óo sì bá wọn dá majẹmu ayérayé.
9Àwọn ọmọ wọn yóo dá yàtọ̀ láàrin orílẹ̀-èdè,
a óo dá arọmọdọmọ wọn mọ̀ láàrin àwọn eniyan,
gbogbo àwọn tí ó bá rí wọn,
yóo gbà pé èmi OLUWA ti bukun wọn.”
10N óo máa yọ̀ ninu OLUWA,#Ifi 21:2
ọkàn mi yóo kún fún ayọ̀ sí Ọlọrun mi.
Nítorí ó ti fi ìgbàlà wọ̀ mí bí ẹ̀wù,
ó sì ti fi òdodo bòmí lára bí aṣọ;
bí ọkọ iyawo tí ó ṣe ara rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́,
ati bí iyawo tí ó ṣe ọ̀ṣọ́ jìngbìnnì.
11Bí ilẹ̀ tíí mú kí ewéko hù jáde,
tí ọgbà sì ń mú kí ohun tí a gbìn sinu rẹ̀ hù,
bẹ́ẹ̀ ni OLUWA Ọlọrun yóo mú kí òdodo ati orin ìyìn yọ jáde
níwájú gbogbo orílẹ̀-èdè.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
AISAYA 61: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010