1
JEREMAYA 8:22
Yoruba Bible
Ṣé kò sí ìwọ̀ra ní Gileadi ni? Àbí kò sí oníwòsàn níbẹ̀? Kí ló dé tí àìsàn àwọn eniyan mi kò sàn?
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí JEREMAYA 8:22
2
JEREMAYA 8:4
OLUWA ní kí n sọ fún wọn pé, “Ṣé bí eniyan bá ṣubú kì í tún dìde mọ́? Àbí bí eniyan bá ṣìnà, kì í pada mọ́?
Ṣàwárí JEREMAYA 8:4
3
JEREMAYA 8:7
Ẹyẹ àkọ̀ tí ń fò lójú ọ̀run pàápàá mọ àkókò rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ sì ni àdàbà, ati lékèélékèé, ati alápàáǹdẹ̀dẹ̀; wọ́n mọ àkókò tí ó yẹ láti ṣípò pada. Ṣugbọn àwọn eniyan mi kò mọ òfin OLUWA.
Ṣàwárí JEREMAYA 8:7
4
JEREMAYA 8:6
Mo tẹ́tí sílẹ̀ kí n gbọ́ tiwọn, ṣugbọn wọn kò sọ̀rọ̀ rere. Kò sí ẹni tí ó kẹ́dùn iṣẹ́ ibi rẹ̀, kí ó wí pé, ‘Kí ni mo ṣe yìí?’ Olukuluku tẹ̀ sí ọ̀nà tí ó wù ú, bí ẹṣin tí ń sáré lọ ojú ogun.
Ṣàwárí JEREMAYA 8:6
5
JEREMAYA 8:9
Ojú yóo ti àwọn ọlọ́gbọ́n: ìdààmú yóo bá wọn, ọwọ́ yóo sì tẹ̀ wọ́n. Wò ó! Wọ́n ti kọ ọ̀rọ̀ OLUWA sílẹ̀, ọgbọ́n wo ni ó kù tí wọ́n gbọ́n?
Ṣàwárí JEREMAYA 8:9
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò