1
MAKU 8:35
Yoruba Bible
Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ gba ẹ̀mí rẹ̀ là, yóo pàdánù rẹ̀. Ṣugbọn ẹnikẹ́ni tí ó bá pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ nítorí mi ati nítorí ìyìn rere, yóo gba ẹ̀mí rẹ̀ là.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí MAKU 8:35
2
MAKU 8:36
Nítorí anfaani kí ni ó jẹ́ fún eniyan kí ó jèrè gbogbo dúkìá ayé yìí, ṣugbọn kí ó pàdánù ẹ̀mí rẹ̀?
Ṣàwárí MAKU 8:36
3
MAKU 8:34
Ó pe àwọn eniyan ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó wí fún wọn pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ máa tọ̀ mí lẹ́yìn, ó níláti gbàgbé ara rẹ̀, kí ó gbé agbelebu rẹ̀, kí ó wá máa tẹ̀lé mi.
Ṣàwárí MAKU 8:34
4
MAKU 8:37-38
Kí ni eniyan lè fi ṣe pàṣípààrọ̀ ẹ̀mí rẹ̀? Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá tijú èmi ati ọ̀rọ̀ mi ní àkókò burúkú yìí, tí àwọn eniyan kò ka nǹkan Ọlọrun sí, Ọmọ-Eniyan yóo tijú rẹ̀ nígbà tí ó bá dé ninu ògo Baba rẹ̀ pẹlu àwọn angẹli mímọ́.”
Ṣàwárí MAKU 8:37-38
5
MAKU 8:29
Ó wá bi wọ́n pé, “Ẹ̀yin ńkọ́, ta ni ẹ̀yin ń pè mí?” Peteru dá a lóhùn pé, “Ìwọ ni Kristi náà.”
Ṣàwárí MAKU 8:29
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò