1
MAKU 9:23
Yoruba Bible
Jesu wí fún un pé, “Ọ̀ràn bí èmi bá lè ṣe é kọ́ yìí, ohun gbogbo ni ó ṣeéṣe fún ẹni tí ó bá gbàgbọ́.”
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí MAKU 9:23
2
MAKU 9:24
Lẹ́sẹ̀ kan náà baba ọmọ náà kígbe pé, “Mo gbàgbọ́; ràn mí lọ́wọ́ níbi tí igbagbọ mi kù kí ó tó.”
Ṣàwárí MAKU 9:24
3
MAKU 9:28-29
Nígbà tí Jesu wọ inú ilé, tí ó ku òun ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, wọ́n ń bi í pé, “Kí ló dé tí àwa kò fi lè lé ẹ̀mí náà jáde?” Ó dá wọn lóhùn pé, “Irú èyí kò ṣe é lé jáde, àfi pẹlu adura [ati ààwẹ̀.”]
Ṣàwárí MAKU 9:28-29
4
MAKU 9:50
“Iyọ̀ dára, ṣugbọn bí iyọ̀ bá di òbu, báwo ni yóo ṣe tún lè dùn mọ́? “Ẹ ní iyọ̀ ninu ara yín, nígbà náà ni alaafia yóo wà láàrin yín.”
Ṣàwárí MAKU 9:50
5
MAKU 9:37
“Ẹnikẹ́ni tí ó bá gba ọ̀kan ninu àwọn ọmọ kékeré yìí nítorí orúkọ mi, èmi ni ó gbà. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà mí, kì í ṣe èmi ni ó gbà, ṣugbọn ó gba ẹni tí ó rán mi wá sí ayé.”
Ṣàwárí MAKU 9:37
6
MAKU 9:41
Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá fun yín ní omi mu nítorí tèmi, nítorí pé ẹ jẹ́ ti Kristi, mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé yóo rí èrè rẹ̀ gbà.
Ṣàwárí MAKU 9:41
7
MAKU 9:42
“Ẹnikẹ́ni tí ó bá mú ọ̀kan ninu àwọn kéékèèké wọnyi tí ó gbà mí gbọ́ kọsẹ̀, ó sàn fún un kí á so ọlọ ńlá mọ́ ọn lọ́rùn, kí á gbé e sọ sinu òkun.
Ṣàwárí MAKU 9:42
8
MAKU 9:47
Bí ojú rẹ bá mú ọ kọsẹ̀, yọ ọ́ sọnù, ó sàn fún ọ kí o wọ ìjọba Ọlọrun pẹlu ojú kan jù pé kí o ní ojú mejeeji kí a sì sọ ọ́ sinu iná
Ṣàwárí MAKU 9:47
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò