1
NỌMBA 22:28
Yoruba Bible
Nígbà náà ni OLUWA la kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà lóhùn ó sì sọ̀rọ̀ bí eniyan, ó sì sọ fún Balaamu pé, “Kí ni mo fi ṣe ọ́ tí o fi lù mí nígbà mẹta?”
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí NỌMBA 22:28
2
NỌMBA 22:31
Nígbà náà ni OLUWA la Balaamu lójú láti rí angẹli tí ó dúró lójú ọ̀nà pẹlu idà lọ́wọ́ rẹ̀, Balaamu sì dojúbolẹ̀.
Ṣàwárí NỌMBA 22:31
3
NỌMBA 22:32
Angẹli náà bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ló dé tí o fi lu kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ nígbà mẹta? Mo wá láti dínà fún ọ nítorí pé kò yẹ kí o rin ìrìn àjò yìí.
Ṣàwárí NỌMBA 22:32
4
NỌMBA 22:30
Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà dáhùn pé, “Ṣebí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ ni mí, tí o sì ti ń gùn mí láti iye ọjọ́ yìí títí di òní? Ǹjẹ́ mo hu irú ìwà báyìí sí ọ rí?” Balaamu dáhùn pé, “Rárá o.”
Ṣàwárí NỌMBA 22:30
5
NỌMBA 22:29
Balaamu dáhùn pé, “Nítorí tí ò ń fi mí ṣẹ̀sín, bí ó bá jẹ́ pé idà wà lọ́wọ́ mi ni, ǹ bá ti pa ọ́.”
Ṣàwárí NỌMBA 22:29
6
NỌMBA 22:27
Nígbà tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà rí angẹli náà, ó wó lulẹ̀ lábẹ́ Balaamu. Inú bí Balaamu gidigidi, ó sì fi ọ̀pá rẹ̀ na kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà.
Ṣàwárí NỌMBA 22:27
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò