1
ÌWÉ ÒWE 22:6
Yoruba Bible
Tọ́ ọmọ rẹ sí ọ̀nà tí ó yẹ kí ó máa rìn, bí ó bá dàgbà tán, kò ní kúrò ninu rẹ̀.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 22:6
2
ÌWÉ ÒWE 22:4
Èrè ìrẹ̀lẹ̀ ati ìbẹ̀rù OLUWA ni ọrọ̀, ọlá, ati ìyè.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 22:4
3
ÌWÉ ÒWE 22:1
Orúkọ rere dára láti yàn ju ọrọ̀ pupọ lọ, kí á rí ojurere sì dára ju kí á ní fadaka ati wúrà lọ.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 22:1
4
ÌWÉ ÒWE 22:24
Má bá oníbìínú eniyan kẹ́gbẹ́, má sì bá onínúfùfù da nǹkan pọ̀.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 22:24
5
ÌWÉ ÒWE 22:9
Olójú àánú yóo rí ibukun gbà, nítorí pé ó ń fún talaka ninu oúnjẹ rẹ̀.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 22:9
6
ÌWÉ ÒWE 22:3
Ọlọ́gbọ́n rí ibi, ó farapamọ́, ṣugbọn òpè ń bá tirẹ̀ lọ láìbìkítà, ó sì kó sinu ìyọnu.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 22:3
7
ÌWÉ ÒWE 22:7
Ọlọ́rọ̀ máa ń jọba lé talaka lórí, ẹni tí ó lọ yá owó sì ni ẹrú ẹni tí ó yá a lówó.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 22:7
8
ÌWÉ ÒWE 22:2
Ọlọ́rọ̀ ati talaka pàdé, OLUWA ló dá ekinni-keji wọn.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 22:2
9
ÌWÉ ÒWE 22:22-23
Má ja talaka lólè, nítorí pé ó jẹ́ talaka, má sì dájọ́ èké fún ẹni tí ara ń ni. Nítorí OLUWA yóo gbèjà wọn, yóo fìyà jẹ àwọn tí wọn ń jẹ wọ́n níyà.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 22:22-23
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò