1
ÌWÉ ÒWE 27:17
Yoruba Bible
Bí irin ti ń pọ́n irin, bẹ́ẹ̀ ni eniyan ń kẹ́kọ̀ọ́ lára ẹnìkejì rẹ̀.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 27:17
2
ÌWÉ ÒWE 27:1
Má lérí nípa ọ̀la, nítorí o kò mọ ohun tí ó lè ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 27:1
3
ÌWÉ ÒWE 27:6
Òtítọ́ ọ̀rọ̀ ọ̀rẹ́ ẹni lè dunni bí ọgbẹ́; ṣugbọn ẹ̀tàn ni ìfẹnukonu ọ̀tá.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 27:6
4
ÌWÉ ÒWE 27:19
Bí omi tíí fi bí ojú ẹni ti rí han ni, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn eniyan ń fi irú ẹni tí eniyan jẹ́ hàn.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 27:19
5
ÌWÉ ÒWE 27:2
Ẹlòmíràn ni kí o jẹ́ kí ó yìn ọ́, má yin ara rẹ, jẹ́ kí ó ti ẹnu ẹlòmíràn jáde, kí ó má jẹ́ láti ẹnu ìwọ alára.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 27:2
6
ÌWÉ ÒWE 27:5
Ìbáwí ní gbangba sàn ju ìfẹ́ kọ̀rọ̀ lọ.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 27:5
7
ÌWÉ ÒWE 27:15
Iyawo oníjà dàbí omi òjò, tí ń kán tó! Tó! Tó! Láì dáwọ́ dúró
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 27:15
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò