1
ÌWÉ ÒWE 3:5-6
Yoruba Bible
Fi tọkàntọkàn gbẹ́kẹ̀lé OLUWA, má sì tẹ̀lé ìmọ̀ ara rẹ. Mọ Ọlọrun ní gbogbo ọ̀nà rẹ, yóo sì mú kí ọ̀nà rẹ tọ́.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 3:5-6
2
ÌWÉ ÒWE 3:7
Má ṣe jẹ́ ọlọ́gbọ́n lójú ara rẹ, bẹ̀rù OLUWA, kí o sì yẹra fún ibi.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 3:7
3
ÌWÉ ÒWE 3:9-10
Fi ohun ìní rẹ bọ̀wọ̀ fún OLUWA pẹlu gbogbo àkọ́so oko rẹ. Nígbà náà ni àká rẹ yóo kún bámúbámú, ìkòkò waini rẹ yóo sì kún àkúnya.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 3:9-10
4
ÌWÉ ÒWE 3:3
Má jẹ́ kí ìwà ìṣòótọ́ kí ó fi ọ́ sílẹ̀, so àánú ati òtítọ́ mọ́ ọrùn rẹ, kọ wọ́n sí oókan àyà rẹ.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 3:3
5
ÌWÉ ÒWE 3:11-12
Ọmọ mi, má ṣe kẹ́gàn ìtọ́ni OLUWA, má sì ṣe jẹ́ kí ìbáwí rẹ̀ sú ọ. Nítorí ẹni tí OLUWA bá fẹ́ níí báwí gẹ́gẹ́ bí baba tí máa ń bá ọmọ rẹ̀ tí ó bá fẹ́ràn wí.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 3:11-12
6
ÌWÉ ÒWE 3:1-2
Ọmọ mi, má ṣe gbàgbé ẹ̀kọ́ tí mo kọ́ ọ, sì pa òfin mi mọ́ lọ́kàn rẹ, nítorí wọn óo fún ọ ní ẹ̀mí gígùn ati ọpọlọpọ alaafia.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 3:1-2
7
ÌWÉ ÒWE 3:13-15
Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó wá ọgbọ́n rí, ati ẹni tí ó ní òye. Nítorí èrè rẹ̀ dára ju èrè orí fadaka ati ti wúrà lọ. Ọgbọ́n níye lórí ó ju ohun ọ̀ṣọ́ olówó iyebíye lọ, kò sí ohun tí o lè fi wé e, ninu gbogbo ohun tí ọkàn rẹ lè fẹ́.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 3:13-15
8
ÌWÉ ÒWE 3:27
Má ṣe fa ọwọ́ ire sẹ́yìn lọ́dọ̀ àwọn tí ó tọ́ sí, nígbà tí ó bá wà ní ìkáwọ́ rẹ láti ṣe é.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 3:27
9
ÌWÉ ÒWE 3:19
Ọgbọ́n ni OLUWA fi fi ìdí ayé sọlẹ̀, òye ni ó sì fi dá ọ̀run.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 3:19
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò