1
ÌWÉ ÒWE 4:23
Yoruba Bible
Ṣọ́ra pẹlu èrò ọkàn rẹ, nítorí èrò ọkàn ni orísun ìyè.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 4:23
2
ÌWÉ ÒWE 4:26
Kíyèsí ìrìn ẹsẹ̀ rẹ, gbogbo ọ̀nà rẹ yóo sì là.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 4:26
3
ÌWÉ ÒWE 4:24
Má lọ́wọ́ ninu ọ̀rọ̀ ìsọkúsọ, sì jìnnà sí ọ̀rọ̀ àgàbàgebè.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 4:24
4
ÌWÉ ÒWE 4:7
Bí o bá fẹ́ gbọ́n, bẹ̀rẹ̀ sí kọ́gbọ́n, ohun yòówù tí o lè tún ní, ọgbọ́n ló jù, nítorí náà jẹ́ ọlọ́gbọ́n.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 4:7
5
ÌWÉ ÒWE 4:18-19
Ṣugbọn ọ̀nà olódodo dàbí ìmọ́lẹ̀ àfẹ̀mọ́júmọ́, tí ń mọ́lẹ̀ sí i láti ìdájí títí tí ilẹ̀ yóo fi mọ́ kedere. Ọ̀nà eniyan burúkú dàbí òkùnkùn biribiri, wọn kò mọ ohun tí wọn yóo dìgbò lù.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 4:18-19
6
ÌWÉ ÒWE 4:6
Má ṣe kọ ọgbọ́n sílẹ̀, yóo pa ọ́ mọ́, fẹ́ràn rẹ̀, yóo sì dáàbò bò ọ́.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 4:6
7
ÌWÉ ÒWE 4:13
Di ẹ̀kọ́ mú ṣinṣin, má jẹ́ kí ó bọ́, pa á mọ́, nítorí òun ni ìyè rẹ.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 4:13
8
ÌWÉ ÒWE 4:14
Má ṣe gba ọ̀nà ẹni ibi, má sì ṣe rin ọ̀nà eniyan burúkú.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 4:14
9
ÌWÉ ÒWE 4:1
Ẹ̀yin ọmọ, ẹ gbọ́ ẹ̀kọ́ baba yín, ẹ tẹ́tí sílẹ̀, kí ẹ lè ní ìmọ̀
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 4:1
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò