1
ORIN DAFIDI 139:14
Yoruba Bible
Mo yìn ọ́, nítorí pé ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ ati ẹni ìyanu ni ọ́; ìyanu ni iṣẹ́ ọwọ́ rẹ! O mọ̀ mí dájú.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí ORIN DAFIDI 139:14
2
ORIN DAFIDI 139:23-24
Wádìí mi, Ọlọrun, kí o mọ ọkàn mi; yẹ̀ mí wò, kí o sì mọ èrò ọkàn mi. Wò ó bí ọ̀nà ibi kan bá wà tí mò ń tọ̀, kí o sì tọ́ mi sí ọ̀nà ayérayé.
Ṣàwárí ORIN DAFIDI 139:23-24
3
ORIN DAFIDI 139:13
Nítorí ìwọ ni o dá inú mi, ìwọ ni o sọ mí di odidi ní inú ìyá mi.
Ṣàwárí ORIN DAFIDI 139:13
4
ORIN DAFIDI 139:16
Kí á tó dá mi tán ni o ti rí mi, o ti kọ iye ọjọ́ tí a pín fún mi sinu ìwé rẹ, kí ọjọ́ ayé mi tilẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ rárá.
Ṣàwárí ORIN DAFIDI 139:16
5
ORIN DAFIDI 139:1
OLUWA, o ti yẹ̀ mí wò, o sì mọ̀ mí.
Ṣàwárí ORIN DAFIDI 139:1
6
ORIN DAFIDI 139:7
Níbo ni mo lè sá lọ, tí ẹ̀mí rẹ kò ní sí níbẹ̀? Níbo ni mo lè sá gbà tí ojú rẹ kò ní tó mi?
Ṣàwárí ORIN DAFIDI 139:7
7
ORIN DAFIDI 139:2
O mọ ìgbà tí mo jókòó, ati ìgbà tí mo dìde; o mọ èrò ọkàn mi láti òkèèrè réré.
Ṣàwárí ORIN DAFIDI 139:2
8
ORIN DAFIDI 139:4
Kódà kí n tó sọ ọ̀rọ̀ jáde lẹ́nu, OLUWA, o ti mọ gbogbo nǹkan tí mo fẹ́ sọ patapata.
Ṣàwárí ORIN DAFIDI 139:4
9
ORIN DAFIDI 139:3
O yẹ ìrìn ẹsẹ̀ mi ati àbọ̀sinmi mi wò; gbogbo ọ̀nà mi ni o sì mọ̀.
Ṣàwárí ORIN DAFIDI 139:3
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò