1
ÌFIHÀN 16:15
Yoruba Bible
“Bí olè ni mò ń bọ̀. Ẹni tí ó bá ń ṣọ́nà ṣe oríire, tí olúwarẹ̀ wọ aṣọ rẹ̀, kí ó má baà sí ní ìhòòhò, kí ojú má baà tì í níwájú àwọn eniyan.”
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí ÌFIHÀN 16:15
2
ÌFIHÀN 16:12
Angẹli kẹfa da ohun tí ó wà ninu àwo rẹ̀ sórí odò ńlá tí wọn ń pè ní Yufurate, ni omi rẹ̀ bá gbẹ láti fi ọ̀nà sílẹ̀ fún àwọn ọba tí ń bọ̀ láti ìhà ìlà oòrùn.
Ṣàwárí ÌFIHÀN 16:12
3
ÌFIHÀN 16:14
Ẹ̀mí Èṣù ni àwọn ẹ̀mí náà, wọ́n sì lè ṣe ohun abàmì. Wọ́n jáde lọ sọ́dọ̀ àwọn ọba ní gbogbo ayé, láti kó wọn jọ fún ogun ní ọjọ́ ńlá ti Ọlọrun alágbára jùlọ.
Ṣàwárí ÌFIHÀN 16:14
4
ÌFIHÀN 16:13
Mo wá rí àwọn ẹ̀mí burúkú mẹta kan, wọ́n dàbí ọ̀pọ̀lọ́ ní ẹnu Ẹranko Ewèlè náà, ati ní ẹnu wolii èké náà.
Ṣàwárí ÌFIHÀN 16:13
5
ÌFIHÀN 16:9
Oòrùn bẹ̀rẹ̀ sí jó àwọn eniyan bí iná ńlá, wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí sọ ọ̀rọ̀ àfojúdi sí orúkọ Ọlọrun tí ó ní àṣẹ lórí àwọn àjàkálẹ̀ àrùn wọnyi, dípò kí wọ́n ronupiwada, kí wọ́n fi ògo fún un.
Ṣàwárí ÌFIHÀN 16:9
6
ÌFIHÀN 16:2
Angẹli kinni lọ, ó bá da ohun tí ó wà ninu àwo rẹ̀ sinu ayé. Ni egbò rírà tí ń rùn bá dà bo àwọn tí wọ́n ní àmì ẹranko náà ní ara, tí wọ́n sì ń júbà ère rẹ̀.
Ṣàwárí ÌFIHÀN 16:2
7
ÌFIHÀN 16:16
Ó bá kó àwọn ọba wọnyi jọ sí ibìkan tí ń jẹ́ Amagedoni ní èdè Heberu.
Ṣàwárí ÌFIHÀN 16:16
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò