1
I. Kor 13:4-5
Bibeli Mimọ
Ifẹ a mã mu suru, a si mã ṣeun; ifẹ kì iṣe ilara; ifẹ kì isọrọ igberaga, kì ifẹ̀, Kì ihuwa aitọ́, kì iwá ohun ti ara rẹ̀, a kì imu u binu, bẹ̃ni kì igbiro ohun buburu
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí I. Kor 13:4-5
2
I. Kor 13:7
A mã farada ohun gbogbo, a mã gbà ohun gbogbo gbọ́, a mã reti ohun gbogbo, a mã fàiyarán ohun gbogbo.
Ṣàwárí I. Kor 13:7
3
I. Kor 13:6
Kì iyọ̀ si aiṣododo, ṣugbọn a mã yọ̀ ninu otitọ
Ṣàwárí I. Kor 13:6
4
I. Kor 13:13
Njẹ nisisiyi igbagbọ́, ireti, ati ifẹ mbẹ, awọn mẹta yi: ṣugbọn eyiti o tobi jù ninu wọn ni ifẹ.
Ṣàwárí I. Kor 13:13
5
I. Kor 13:8
Ifẹ kì iyẹ̀ lai: ṣugbọn biobaṣepe isọtẹlẹ ni, nwọn ó dopin; biobaṣepe ẹ̀bun ahọn ni, nwọn ó dakẹ; biobaṣepe ìmọ ni, yio di asan.
Ṣàwárí I. Kor 13:8
6
I. Kor 13:1
BI mo tilẹ nfọ oniruru ede ati ti angẹli, ti emi kò si ni ifẹ, emi dabi idẹ ti ndún, tabi bi kimbali olohùn goro.
Ṣàwárí I. Kor 13:1
7
I. Kor 13:2
Bi mo si ni ẹbun isọtẹlẹ, ti mo si ni oye gbogbo ohun ijinlẹ, ati gbogbo ìmọ; bi mo si ni gbogbo igbagbọ́, tobẹ̃ ti mo le ṣí awọn òke nla nipò, ti emi kò si ni ifẹ, emi kò jẹ nkan.
Ṣàwárí I. Kor 13:2
8
I. Kor 13:3
Bi mo si nfi gbogbo ohun ini mi bọ́ awọn talaka, bi mo si fi ara mi funni lati sun, ti emi kò si ni ifẹ, kò li ere kan fun mi.
Ṣàwárí I. Kor 13:3
9
I. Kor 13:11
Nigbati mo wà li ewe, emi a mã sọ̀rọ bi èwe, emi a mã moye bi ewe, emi a mã gbero bi ewe: ṣugbọn nigbati mo di ọkunrin tan, mo fi ìwa ewe silẹ.
Ṣàwárí I. Kor 13:11
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò