1
I. Kor 12:7
Bibeli Mimọ
Ṣugbọn a nfi ifihàn Ẹmí fun olukuluku enia lati fi jère.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí I. Kor 12:7
2
I. Kor 12:27
Njẹ ara Kristi li ẹnyin iṣe, olukuluku nyin si jẹ ẹ̀ya ara rẹ̀.
Ṣàwárí I. Kor 12:27
3
I. Kor 12:26
Bi ẹ̀ya kan ba si njìya, gbogbo ẹ̀ya a si jùmọ ba a jìya; tabi bi a ba mbọla fun ẹ̀ya kan, gbogbo ẹ̀ya a jùmọ ba a yọ̀.
Ṣàwárí I. Kor 12:26
4
I. Kor 12:8-10
Nitoriti a fi ọ̀rọ ọgbọ́n fun ẹnikan nipa Ẹmí; ati fun ẹlomiran ọ̀rọ-ìmọ nipa Ẹmí kanna; Ati fun ẹlomiran igbagbọ́ nipa Ẹmí kanna; ati fun ẹlomiran ẹ̀bun imularada nipa Ẹmí kanna; Ati fun ẹlomiran iṣẹ iyanu iṣe; ati fun ẹlomiran isọtẹlẹ; ati fun ẹlomiran ìmọ ẹmí yatọ; ati fun ẹlomiran onirũru ède; ati fun ẹlomiran itumọ̀ ède
Ṣàwárí I. Kor 12:8-10
5
I. Kor 12:11
Ṣugbọn gbogbo wọnyi li ẹnikan nì, ani Ẹmí kanna nṣe, o npín fun olukuluku gẹgẹ bi o ti wù u.
Ṣàwárí I. Kor 12:11
6
I. Kor 12:25
Ki ìyapa ki o máṣe si ninu ara; ṣugbọn ki awọn ẹ̀ya ara ki o le mã ṣe aniyan kanna fun ara wọn.
Ṣàwárí I. Kor 12:25
7
I. Kor 12:4-6
Njẹ onirũru ẹ̀bun li o wà, ṣugbọn Ẹmí kanna ni. Onirũru iṣẹ-iranṣẹ li ó si wà, Oluwa kanna si ni. Onirũru iṣẹ li o si wà, ṣugbọn Ọlọrun kanna ni ẹniti nṣiṣẹ gbogbo wọn ninu gbogbo wọn.
Ṣàwárí I. Kor 12:4-6
8
I. Kor 12:28
Ọlọrun si gbé awọn miran kalẹ ninu ijọ, ekini awọn aposteli, ekeji awọn woli, ẹkẹta awọn olukọni, lẹhinna iṣẹ iyanu, lẹhinna ẹ̀bun imularada, iranlọwọ, ẹbùn akoso, onirũru ède.
Ṣàwárí I. Kor 12:28
9
I. Kor 12:14
Nitoripe ara kì iṣe ẹ̀ya kan, bikoṣe pupọ.
Ṣàwárí I. Kor 12:14
10
I. Kor 12:22
Ṣugbọn awọn ẹ̀ya ara wọnni ti o dabi ẹnipe nwọn ṣe ailera jù, awọn li a kò le ṣe alaini jù
Ṣàwárí I. Kor 12:22
11
I. Kor 12:17-19
Bi gbogbo ara ba jẹ oju, nibo ni igbọràn iba gbé wà? Bi gbogbo rẹ̀ ba si jẹ igbọràn, nibo ni igbõrùn iba gbé wà? Ṣugbọn nisisiyi Ọlọrun ti fi awọn ẹ̀ya sinu ara, olukuluku wọn gẹgẹ bi o ti wù u. Bi gbogbo wọn ba si jẹ ẹ̀ya kan, nibo li ara iba gbé wà?
Ṣàwárí I. Kor 12:17-19
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò