1
I. Joh 2:15-16
Bibeli Mimọ
Ẹ máṣe fẹran aiye, tabi ohun ti mbẹ ninu aiye. Bi ẹnikẹni ba fẹran aiye, ifẹ ti Baba kò si ninu rẹ̀. Nitori ohun gbogbo ti mbẹ li aiye, ifẹkufẹ ara, ati ifẹkufẹ oju, ati irera aiye, ki iṣe ti Baba, bikoṣe ti aiye.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí I. Joh 2:15-16
2
I. Joh 2:17
Aiye si nkọja lọ, ati ifẹkufẹ rẹ̀: ṣugbọn ẹniti o ba nṣe ifẹ Ọlọrun ni yio duro lailai.
Ṣàwárí I. Joh 2:17
3
I. Joh 2:6
Ẹniti o ba wipe on ngbé inu rẹ̀, on na pẹlu si yẹ lati mã rìn gẹgẹ bi on ti rìn.
Ṣàwárí I. Joh 2:6
4
I. Joh 2:1
ẸNYIN ọmọ mi, iwe nkan wọnyi ni mo kọ si nyin, ki ẹ má bã dẹṣẹ̀. Bi ẹnikẹni ba si dẹṣẹ̀, awa ni alagbawi lọdọ Baba, Jesu Kristi olododo
Ṣàwárí I. Joh 2:1
5
I. Joh 2:4
Ẹniti o ba wipe, emi mọ̀ ọ, ti kò si pa ofin rẹ̀ mọ́, eke ni, otitọ kò si si ninu rẹ̀.
Ṣàwárí I. Joh 2:4
6
I. Joh 2:3
Nipa eyi li a si mọ̀ pe awa mọ̀ ọ, bi awa ba npa ofin rẹ̀ mọ́.
Ṣàwárí I. Joh 2:3
7
I. Joh 2:9
Ẹniti o ba wipe on mbẹ ninu imọlẹ, ti o si korira arakunrin rẹ̀, o mbẹ ninu òkunkun titi fi di isisiyi.
Ṣàwárí I. Joh 2:9
8
I. Joh 2:22
Tani eke, bikoṣe ẹniti o ba sẹ́ pe Jesu kì iṣe Kristi? Eleyi ni Aṣodisi-Kristi, ẹniti o ba sẹ́ Baba ati Ọmọ.
Ṣàwárí I. Joh 2:22
9
I. Joh 2:23
Ẹnikẹni ti o ba sẹ́ Ọmọ, on na ni kò gbà Baba: ṣugbọn ẹniti o ba jẹwọ Ọmọ, o gbà Baba pẹlu.
Ṣàwárí I. Joh 2:23
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò