1
I. Joh 3:18
Bibeli Mimọ
Ẹnyin ọmọ mi, ẹ máṣe jẹ ki a fi ọrọ tabi ahọn fẹran, bikoṣe ni iṣe ati li otitọ.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí I. Joh 3:18
2
I. Joh 3:16
Nipa eyi li awa mọ̀ ifẹ nitoriti o fi ẹmí rẹ̀ lelẹ fun wa: o si yẹ ki awa fi ẹmí wa lelẹ fun awọn ará.
Ṣàwárí I. Joh 3:16
3
I. Joh 3:1
Ẹ wo irú ifẹ ti Baba fi fẹ wa, ti a fi npè wa ni ọmọ Ọlọrun; bẹ̃ li a sa jẹ. Nitori eyi li aiye kò ṣe mọ̀ wa, nitoriti ko mọ̀ ọ.
Ṣàwárí I. Joh 3:1
4
I. Joh 3:8
Ẹniti o ba ndẹṣẹ ti Èṣu ni; nitori lati àtetekọṣe ni Èṣu ti ndẹṣẹ. Nitori eyi li Ọmọ Ọlọrun ṣe farahàn, ki o le pa iṣẹ Èṣu run.
Ṣàwárí I. Joh 3:8
5
I. Joh 3:9
Ẹnikẹni ti a ti ipa Ọlọrun bí, ki idẹṣẹ; nitoriti irú rẹ̀ ngbe inu rẹ̀: kò si le dẹṣẹ nitoripe a ti ti ipa Ọlọrun bi i.
Ṣàwárí I. Joh 3:9
6
I. Joh 3:17
Ṣugbọn ẹniti o ba ni ohun ini aiye, ti o si ri arakunrin rẹ̀ ti iṣe alaini, ti o si sé ilẹkun ìyọ́nu rẹ̀ mọ ọ, bawo ni ifẹ Ọlọrun ti ngbé inu rẹ̀?
Ṣàwárí I. Joh 3:17
7
I. Joh 3:24
Ẹniti o ba si pa ofin rẹ̀ mọ́ ngbé inu rẹ̀, ati on ninu rẹ̀. Ati nipa eyi li awa mọ̀ pe o ngbé inu wa, nipa Ẹmí ti o fifun wa.
Ṣàwárí I. Joh 3:24
8
I. Joh 3:10
Ninu eyi li awọn ọmọ Ọlọrun nfarahan, ati awọn ọmọ Èṣu: ẹnikẹni ti kò ba nṣe ododo kì iṣe ti Ọlọrun, ati ẹniti kò fẹràn arakunrin rẹ̀.
Ṣàwárí I. Joh 3:10
9
I. Joh 3:11
Nitori eyi ni iṣẹ ti ẹnyin ti gbọ́ li àtetekọṣe, ki awa ki o fẹràn ara wa.
Ṣàwárí I. Joh 3:11
10
I. Joh 3:13
Ki ẹnu ki o máṣe yà nyin, ẹnyin ará mi, bi aiye ba korira nyin.
Ṣàwárí I. Joh 3:13
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò