1
II. Kor 4:18
Bibeli Mimọ
Niwọn bi a kò ti wò ohun ti a nri, bikoṣe ohun ti a kò ri: nitori ohun ti a nri ni ti igba isisiyi; ṣugbọn ohun ti a kò ri ni ti aiyeraiye.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí II. Kor 4:18
2
II. Kor 4:16-17
Nitori eyi ni ãrẹ̀ kò ṣe mu wa; ṣugbọn bi ọkunrin ti ode wa ba nparun, sibẹ ọkunrin ti inu wa ndi titun li ojojumọ́. Nitori ipọnju wa ti o fẹrẹ, ti iṣe fun iṣẹ́ju kan, o nṣiṣẹ ogo ainipẹkun ti o pọ̀ rekọja fun wa.
Ṣàwárí II. Kor 4:16-17
3
II. Kor 4:8-9
A npọn wa loju niha gbogbo, ṣugbọn ara kò ní wa: a ndãmú wa, ṣugbọn a kò sọ ireti nù. A nṣe inunibini si wa, ṣugbọn a kò kọ̀ wa silẹ; a nrẹ̀ wa silẹ, ṣugbọn a kò si pa wa run
Ṣàwárí II. Kor 4:8-9
4
II. Kor 4:7
Ṣugbọn awa ni iṣura yi ninu ohun èlo amọ̀, ki ọlá nla agbara na ki o le ṣe ti Ọlọrun, ki o má ti ọdọ wa wá.
Ṣàwárí II. Kor 4:7
5
II. Kor 4:4
Ninu awọn ẹniti ọlọrun aiye yi ti sọ ọkàn awọn ti kò gbagbọ́ di afọju, ki imọlẹ ihinrere Kristi ti o logo, ẹniti iṣe aworan Ọlọrun, ki o máṣe mọlẹ ninu wọn.
Ṣàwárí II. Kor 4:4
6
II. Kor 4:6
Nitori Ọlọrun, ẹniti o wipe ki imọlẹ ki o mọlẹ lati inu òkunkun jade, on li o ti nmọlẹ li ọkàn wa, lati fun wa ni imọlẹ ìmọ ogo Ọlọrun li oju Jesu Kristi.
Ṣàwárí II. Kor 4:6
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò