1
II. A. Ọba 4:2
Bibeli Mimọ
Eliṣa si wi fun u pe, Kini emi o ṣe fun ọ? Wi fun mi, kini iwọ ni ninu ile? On si wipe, Iranṣẹbinrin rẹ kò ni nkankan ni ile, bikòṣe ikòko ororo kan.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí II. A. Ọba 4:2
2
II. A. Ọba 4:1
OBIRIN kan ninu awọn obinrin ọmọ awọn woli ke ba Eliṣa wipe, Iranṣẹ rẹ, ọkọ mi kú; iwọ si mọ̀ pe iranṣẹ rẹ bẹ̀ru Oluwa: awọn onigbèse si wá lati mu awọn ọmọ mi mejeji li ẹrú.
Ṣàwárí II. A. Ọba 4:1
3
II. A. Ọba 4:3
On si wipe, Lọ, ki iwọ ki o yá ikòko lọwọ awọn aladugbò rẹ kakiri, ani ikòko ofo; yá wọn, kì iṣe diẹ.
Ṣàwárí II. A. Ọba 4:3
4
II. A. Ọba 4:4
Nigbati iwọ ba si wọle, ki iwọ ki o se ilẹ̀kun mọ ara rẹ, ati mọ awọn ọmọ rẹ, ki o si dà a sinu gbogbo ikòko wọnni, ki iwọ ki o si fi eyiti o kún si apakan.
Ṣàwárí II. A. Ọba 4:4
5
II. A. Ọba 4:6
O si ṣe, nigbati awọn ikòko kún, o wi fun ọmọ rẹ̀ pe, Tun mu ikòko kan fun mi wá. On si wi fun u pe, Kò si ikòko kan mọ. Ororo na si da.
Ṣàwárí II. A. Ọba 4:6
6
II. A. Ọba 4:7
Nigbana li o wá, o si sọ fun enia Ọlọrun na. On si wipe, Lọ, tà ororo na, ki o si san gbèse rẹ, ki iwọ ati awọn ọmọ rẹ ki o si jẹ eyi ti o kù.
Ṣàwárí II. A. Ọba 4:7
7
II. A. Ọba 4:5
O si lọ kuro lọdọ rẹ̀, o si se ilẹ̀kun mọ ara rẹ̀ ati mọ awọn ọmọ rẹ̀, ti ngbe ikòko fun u wá; on si dà a.
Ṣàwárí II. A. Ọba 4:5
8
II. A. Ọba 4:34
On si gòke, o si dubulẹ le ọmọ na, o si fi ẹnu rẹ̀ le ẹnu rẹ̀, ati oju rẹ̀ le oju rẹ̀, ati ọwọ rẹ̀ le ọwọ rẹ̀: on si nà ara rẹ̀ le ọmọ na, ara ọmọ na si di gbigboná.
Ṣàwárí II. A. Ọba 4:34
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò